I KORINTI 14

1Ẹ mã lepa ifẹ, ki ẹ si mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti iṣe ti Ẹmí, ṣugbọn ki ẹ kuku le mã sọtẹlẹ. 2Nitori ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀, kò bá enia sọ̀rọ bikoṣe Ọlọrun: nitori kò si ẹniti o gbọ; ṣugbọn nipa ti Ẹmí o nsọ ohun ijinlẹ: 3Ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ mba awọn enia sọrọ fun imuduro, ati igbiyanju, ati itunu. 4Ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ nfi ẹsẹ ara rẹ̀ mulẹ; ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ nfi ẹsẹ ijọ mulẹ. 5Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́. 6Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́? 7Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi? 8Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun? 9Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu. 10O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ. 11Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi. 12Bẹ̃ si li ẹnyin, bi ẹnyin ti ni itara fun ẹ̀bun ẹmí, ẹ mã ṣe afẹri ati mã pọ si i fun idàgbàsoke ijọ. 13Nitorina jẹ ki ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ gbadura ki o le mã ṣe itumọ̀. 14Nitori bi emi ba ngbadura li ède aimọ̀, ẹmí mi ngbadura, ṣugbọn oye mi jẹ alaileso. 15Njẹ kini rè? Emi o fi ẹmí gbadura, emi o si fi oye gbadura pẹlu: emi o fi ẹmí kọrin, emi o si fi oye kọrin pẹlu. 16Bi bẹ̃kọ, bi iwọ ba súre nipa, ẹmí, bawo ni ẹniti mbẹ ni ipò òpe yio ṣe ṣe Amin si idupẹ rẹ, nigbati kò mọ ohun ti iwọ wi? 17Nitori iwọ dupẹ gidigidi nitõtọ, ṣugbọn a kò fi ẹsẹ ẹnikeji rẹ mulẹ. 18Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ti emi nfọ oniruru ede jù gbogbo nyin lọ: 19Ṣugbọn mo fẹ ki ng kuku fi oye mi sọ ọ̀rọ marun ni ijọ, ki ng le kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu, jù ẹgbãrun ọ̀rọ li ède aimọ̀. 20Ará, ẹ máṣe jẹ ọmọde ni oye: ṣugbọn ẹ jẹ ọmọde li arankan, ṣugbọn ni oye ki ẹ jẹ agba. 21A ti kọ ọ ninu ofin pe, Nipa awọn alahọn miran ati elete miran li emi ó fi bá awọn enia yi sọrọ; sibẹ nwọn kì yio gbọ temi, li Oluwa wi. 22Nitorina awọn ahọn jasi àmi kan, kì iṣe fun awọn ti o gbagbọ́, bikoṣe fun awọn alaigbagbọ́: ṣugbọn isọtẹlẹ kì iṣe fun awọn ti kò gbagbọ́, bikoṣe fun awọn ti o gbagbọ́. 23Njẹ bi gbogbo ijọ ba pejọ si ibi kan, ti gbogbo nwọn si nfi ède fọ̀, bi awọn ti iṣe alailẹkọ́ ati alaigbagbọ́ ba wọle wá, nwọn kì yio ha wipe ẹnyin nṣe wère? 24Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀: 25Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin. 26Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro. 27Bi ẹnikan ba fi ède fọ̀, ki o jẹ enia meji, tabi bi o pọ̀ tan, ki o jẹ mẹta, ati eyini li ọkọ̃kan; si jẹ ki ẹnikan gbufọ. 28Ṣugbọn bi kò ba si ogbufọ, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ninu ijọ; si jẹ ki o mã bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọrọ. 29Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ. 30Bi a bá si fi ohunkohun hàn ẹniti o joko nibẹ, jẹ ki ẹni iṣaju dakẹ. 31Gbogbo nyin le mã sọtẹlẹ li ọkọ̃kan, ki gbogbo nyin le mã kọ ẹkọ ki a le tu gbogbo nyin ni inu. 32Ẹmí awọn woli a si ma tẹriba fun awọn woli. 33Nitori Ọlọrun kì iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia, gẹgẹ bi o ti jẹ ninu gbogbo ijọ enia mimọ́. 34Jẹ ki awọn obinrin nyin dakẹ ninu ijọ: nitori a kò fifun wọn lati sọrọ, ṣugbọn jẹ ki wọn wà labẹ itẹriba, gẹgẹ bi ofin pẹlu ti wi. 35Bi nwọn ba si fẹ kọ́ ohunkohun, ki nwọn ki o bère lọwọ ọkọ wọn ni ile: nitori ohun itiju ni fun awọn obinrin lati mã sọrọ ninu ijọ. 36Kini? lọdọ nyin li ọ̀rọ Ọlọrun ti jade ni? tabi ẹnyin nikan li o tọ̀ wá? 37Bi ẹnikẹni ba ro ara rẹ̀ pe on jẹ woli, tabi on jẹ ẹniti o li ẹmí, jẹ ki nkan wọnyi ti mo kọ si nyin ki o ye e daju pe ofin Oluwa ni nwọn. 38Ṣugbọn bi ẹnikan ba jẹ òpe, ẹ jẹ ki o jẹ òpe. 39Nitorina, ará, ẹ mã fi itara ṣafẹri lati sọtẹlẹ ki ẹ má si ṣe danilẹkun lati fi ède fọ̀. 40Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\