I JOHANU 5

1OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu. 2Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́. 3Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira. 4Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa. 5Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe? 6Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí. 7Nitoripe awọn mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ̀, ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹtẹ̃ta yi si jẹ ọ̀kan. 8Nitoripe awọn mẹta li o njẹri, Ẹmí, ati omi, ati ẹ̀jẹ: awọn mẹtẹ̃ta sì fi ohun ṣọkan. 9Bi awa ba ngbà ẹ̀rí enia, ẹ̀rí Ọlọrun tobi ju: nitọri ẹri Ọlọrun li eyi pe O ti jẹri niti Ọmọ rẹ̀. 10Ẹniti o ba gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́, o ni ẹrí ninu ara rẹ̀: ẹniti kò ba gbà Ọlọrun gbọ́, o ti mu u li eke; nitori kò gbà ẹrí na gbọ́ ti Ọlọrun jẹ niti Ọmọ rẹ̀. 11Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀. 12Ẹniti o ba ni Ọmọ, o ni ìye; ẹniti kò ba si ni Ọmọ Ọlọrun, kò ni ìye. 13Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́. 14Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa: 15Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ́ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ̀ pe awa rí ibere ti awa ti bère lọdọ rẹ̀ gbà. 16Bi ẹnikẹni ba ri arakunrin rẹ̀ ti ndá ẹ̀ṣẹ ti kì iṣe si ikú, on o bère, On o si fun ni ìye fun awọn ti ndá ẹ̀ṣẹ ti ki iṣe si ikú. Ẹṣẹ kan mbẹ si ikú: emi kò wipe ki on ki o gbadura fun eyi. 17Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú. 18Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a. 19Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì. 20Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun. 21Ẹnyin ọmọ mi, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu oriṣa. Amin.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\