II KORINTI 12

1EMI ko le ṣe aiṣogo bi kò tilẹ ṣe anfani. Nitori emi ó wá si iran ati iṣipaya Oluwa. 2Emi mọ̀ ọkunrin kan ninu Kristi ni ọdún mẹrinla sẹhin, (yala ninu ara ni, emi kò mọ̀; tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀; Ọlọrun ni o mọ): a gbé irú enia bẹ̃ lọ si ọ̀run kẹta. 3Emi si ti mọ̀ irú ọkunrin bẹ̃, (yala li ara ni, tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀: Ọlọrun mọ̀) 4Bi a ti gbé e lọ soke si Paradise, ti o si gbọ́ ọ̀rọ ti a kò le sọ, ti kò tọ́ fun enia lati mã sọ. 5Nipa irú ẹni bẹ̃ li emi ó ma ṣogo: ṣugbọn nipa ti emi tikarami emi kì yio ṣogo, bikoṣe ninu ailera mi. 6Nitoripe bi emi tilẹ nfẹ mã ṣogo, emi kì yio jẹ aṣiwère; nitoripe emi ó sọ otitọ: ṣugbọn mo kọ̀, ki ẹnikẹni ki o má bã fi mi pè jù ohun ti o ri ti emi jẹ lọ, tabi ju eyiti o gbọ lẹnu mi. 7Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja. 8Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi. 9On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi. 10Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara. 11Mo di wère nipa ṣiṣogo; ẹnyin li o mu mi ṣe e: nitoriti o tọ́ ti ẹ ba yìn mi: nitoriti emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na, bi emi kò tilẹ jamọ nkankan. 12Nitõtọ a ti ṣe iṣẹ àmi Aposteli larin nyin ninu sũru gbogbo, ninu iṣẹ àmi, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara. 13Nitori ninu kili ohun ti ẹnyin rẹ̀hin si ijọ miran, bikoṣe niti pe emi tikarami ko jẹ oniyọnu fun nyin? ẹ dari aṣiṣe yi ji mi. 14Kiyesi i, igba kẹta yi ni mo mura tan lati tọ̀ nyin wá; emi kì yio si jẹ oniyọnu fun nyin: nitoriti emi kò wá nkan nyin, bikoṣe ẹnyin tikaranyin: nitoriti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati mã tò iṣura jọ fun awọn õbi wọn, bikoṣe awọn õbi fun awọn ọmọ wọn. 15Emi ó si fi ayọ̀ náwo, emi ó si ná ara mi fun ọkàn nyin nitõtọ; bi mo tilẹ fẹ nyin lọpọlọpọ, diẹ li a ha fẹran mi? 16Ṣugbọn o dara bẹ̃, ti emi kò dẹruba nyin: ṣugbọn bi ọlọgbọn, emi nfi ẹ̀rọ mu nyin. 17Emi ha rẹ́ nyin jẹ nipa ẹnikẹni ninu awọn ti mo rán si nyin bi? 18Mo bẹ̀ Titu, mo si rán arakunrin kan pẹlu rẹ̀; Titu ha rẹ́ nyin jẹ bi? nipa ẹmí kanna kọ́ awa rìn bi? ọ̀na kanna kọ́ awa tọ̀ bi? 19Ẹnyin ha rò pe ni gbogbo akoko yi àwa nṣe àwíjàre niwaju nyin? awa nsọ̀rọ niwaju Ọlọrun ninu Kristi: ṣugbọn awa nṣe ohun gbogbo, olufẹ ọwọn, lati mu nyin duro. 20Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà: 21Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\