II KORINTI 7

1NITORINA, ẹnyin olufẹ, bi a ti ni ileri wọnyi, ẹ jẹ ki a wẹ̀ ara wa mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin ti ara ati ti ẹmí, ki a mã sọ ìwa mimọ́ di pipé ni ìbẹru Ọlọrun. 2Ẹ gbà wa tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹni, a kò bà ẹnikẹni jẹ, a kò rẹ́ ẹnikẹni jẹ. 3Emi kò sọ eyi lati da nyin lẹbi: nitori mo ti wi ṣãjú pe, ẹnyin wà li ọkàn wa ki a le jumọ kú, ati ki a le jumọ wà lãye. 4Mo ni igboiya nla lati ba nyin sọ̀rọ, iṣogo mi lori nyin pọ̀, mo kun fun itunu, mo si nyọ̀ rekọja ninu gbogbo ipọnju wa. 5Nitoripe nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ìja mbẹ lode, ẹ̀ru mbẹ ninu. 6Ṣugbọn ẹniti ntù awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa didé Titu; 7Kì si iṣe nipa didé rẹ̀ nikan, ṣugbọn nipa itunu na pẹlu ti ẹ ti tù u ninu, nigbati o rohin fun wa ifẹ gbigbona nyin, ibanujẹ nyin, ati itara nyin fun mi; bẹni mo si tubọ yọ̀. 8Nitoripe bi mo tilẹ fi iwe mu inu nyin bajẹ, emi kò kãbámọ̀, bi mo tilẹ ti kabamọ rí: nitoriti mo woye pe iwe nì mu nyin banujẹ, bi o tilẹ jẹ pe fun igba diẹ. 9Emi yọ̀ nisisiyi, kì iṣe nitoriti a mu inu nyin bajẹ, ṣugbọn nitoriti a mu inu nyin bajẹ si ironupiwada: nitoriti a mu inu nyin bajẹ bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, ki ẹnyin ki o maṣe tipasẹ wa pàdanù li ohunkohun. 10Nitoripe ibanujẹ ẹni ìwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti kì mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú. 11Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, iṣọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti tó, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na. 12Nitorina, bi mo tilẹ ti kọwe si nyin, emi kò kọ ọ nitori ẹniti o ṣe ohun buburu na, tabi nitori ẹniti a fi ohun buburu na ṣe, ṣugbọn ki aniyan nyin nitori wa le farahan niwaju Ọlọrun. 13Nitorina a ti fi itunu nyin tù wa ninu; ati ni itunu wa a yọ̀ gidigidi nitori ayọ̀ Titu, nitori lati ọdọ gbogbo nyin li a ti tu ẹmi rẹ̀ lara. 14Bi mo tilẹ ti leri ohunkohun fun u nitori nyin, a kò dojuti mi; ṣugbọn gẹgẹ bi awa ti sọ ohun gbogbo fun nyin li otitọ, gẹgẹ bẹ̃li ori ti a lé niwaju Titu si jasi otitọ. 15Iyọ́nu rẹ̀ si di pupọ̀ gidigidi si nyin, bi on ti nranti igbọran gbogbo nyin, bi ẹ ti fi ibẹru ati iwarìri tẹwọgbà a. 16Mo yọ̀ nitoripe li ohun gbogbo mo ni igbẹkẹle ninu nyin.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\