AWỌN APOSTELI 15

1AWỌN ọkunrin kan ti Judea sọkalẹ wá, nwọn si kọ́ awọn arakunrin pe, Bikoṣepe a ba kọ nyin ni ilà bi iṣe Mose, ẹnyin kì yio le là. 2Nigbati iyapa ati iyàn jijà ti mbẹ lãrin Paulu on Barnaba kò si mọ ni ìwọn, awọn arakunrin yàn Paulu on Barnaba, ati awọn miran ninu wọn, ki nwọn goke lọ si Jerusalemu, sọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagba nitori ọ̀ran yi. 3Nitorina nigbati ijọ si sìn wọn de ọna, nwọn là Fenike on Samaria kọja, nwọn nròhin iyipada awọn Keferi: nwọn si fi ayọ̀ nla fun gbogbo awọn arakunrin. 4Nigbati nwọn si de Jerusalemu ijọ ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà tẹwọgba wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti Ọlọrun ti fi wọn ṣe. 5Ṣugbọn awọn kan ti ẹya awọn Farisi ti nwọn gbagbọ́ dide, nwọn nwipe, a ni lati kọ wọn ni ilà, ati lati paṣẹ fun wọn pe ki nwọn ki o mã pa ofin Mose mọ́. 6Ati awọn aposteli ati awọn àgbagbà pejọ lati gbìmọ ọ̀ran yi. 7Nigbati iyàn si di pipọ, Peteru dide, o si wi fun wọn pe, Ará, ẹnyin mọ̀ pe, lati ibẹrẹ Ọlọrun ti yàn ninu nyin, ki awọn Keferi ki o le gbọ́ ọ̀rọ ihinrere li ẹnu mi, ki nwọn si gbagbọ́. 8Ati Ọlọrun, ti iṣe olumọ-ọkàn, o jẹ wọn li ẹrí, o nfun wọn li Ẹmí Mimọ́, gẹgẹ bi awa: 9Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́. 10Njẹ nitorina ẽṣe ti ẹnyin o fi dán Ọlọrun wò, lati fi àjaga bọ̀ awọn ọmọ-ẹhin li ọrùn, eyiti awọn baba wa ati awa kò le rù? 11Ṣugbọn awa gbagbọ́ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa ó là, gẹgẹ bi awọn. 12Gbogbo ajọ si dakẹ, nwọn si fi eti si Barnaba on Paulu, ti nwọn nròhin iṣẹ aṣẹ ati iṣẹ àmi ti Ọlọrun ti ti ọwọ́ wọn ṣe lãrin awọn Keferi. 13Lẹhin ti nwọn si dakẹ, Jakọbu dahùn, wipe, Ará, ẹ gbọ ti emi: 14Simeoni ti rohin bi Ọlọrun li akọṣe ti bojuwò awọn Keferi, lati yàn enia ninu wọn fun orukọ rẹ̀. 15Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe, 16Lẹhin nkan wọnyi li emi o pada, emi o si tún agọ́ Dafidi pa ti o ti wó lulẹ; emi ó si tún ahoro rẹ̀ kọ́, emi ó si gbé e ró: 17Ki awọn enia iyokù le mã wá Oluwa, ati gbogbo awọn Keferi lara ẹniti a npè orukọ mi, 18Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa. 19Njẹ ìmọràn temi ni, ki a máṣe yọ awọn ti o yipada si Ọlọrun lẹnu ninu awọn Keferi: 20Ṣugbọn ki a kọwe si wọn, ki nwọn ki o fà sẹhin kuro ninu ẽri oriṣa, ati kuro ninu àgbere, ati kuro ninu ohun ilọlọrun-pa, ati kuro ninu ẹ̀jẹ. 21Mose nigba atijọ sa ní awọn ti nwasu rẹ̀ ni ilu gbogbo, a ma kà a ninu sinagogu li ọjọjọ isimi. 22Nigbana li o tọ́ loju awọn aposteli, ati awọn àgbagbà pẹlu gbogbo ijọ, lati yàn enia ninu wọn, ati lati ran wọn lọ si Antioku pẹlu Paulu on Barnaba: Juda ti a npè apele rẹ̀ ni Barsaba, ati Sila, ẹniti o l'orukọ ninu awọn arakunrin. 23Nwọn si kọ iwe le wọn lọwọ bayi pe, Awọn aposteli, ati awọn àgbagbà, ati awọn arakunrin, kí awọn arakunrin ti o wà ni Antioku, ati ni Siria, ati ni Kilikia ninu awọn Keferi: 24Niwọnbi awa ti gbọ́ pe, awọn kan ti o ti ọdọ wa jade lọ fi ọ̀rọ yọ nyin li ẹnu, ti nwọn nyi nyin li ọkàn po, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣaima kọ ilà, ati ṣaima pa ofin Mose mọ́: ẹniti awa kò fun li aṣẹ: 25O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn olufẹ wa. 26Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi. 27Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọ̀rọ ẹnu sọ ohun kanna fun nyin. 28Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ: 29Ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹ̀jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ́ kuro, ẹnyin ó ṣe rere. Alafia. 30Njẹ nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn sọkalẹ wá si Antioku: nigbati nwọn si pè apejọ, nwọn fi iwe na fun wọn. 31Nigbati nwọn si kà a, nwọn yọ̀ fun itunu na. 32Bi Juda on Sila tikarawọn ti jẹ woli pẹlu, nwọn fi ọ̀rọ pipọ gbà awọn arakunrin niyanju, nwọn si mu wọn li ọkàn le. 33Nigbati nwọn si pẹ diẹ, awọn arakunrin jọwọ wọn lọwọ lọ li alafia si ọdọ awọn ti o ran wọn. 34Ṣugbọn o wù Sila lati gbé ibẹ̀. 35Paulu on Barnaba si duro diẹ ni Antioku, nwọn nkọ́ni, nwọn si nwasu ọ̀rọ Oluwa, ati awọn pipọ miran pẹlu wọn. 36Lẹhin ijọ melokan, Paulu si sọ fun Barnaba pe, Jẹ ki a tún pada lọ íbẹ awọn arakunrin wa wò, bi nwọn ti nṣe, ni ilu gbogbo ti awa ti wasu ọ̀rọ Oluwa. 37Barnaba si pinnu rẹ̀ lati mu Johanu lọ pẹlu wọn, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Marku. 38Ṣugbọn Paulu rò pe, kò yẹ lati mu u lọ pẹlu wọn, ẹniti o fi wọn silẹ ni Pamfilia, ti kò si ba wọn lọ si iṣẹ na. 39Ìja na si pọ̀ tobẹ̃, ti nwọn yà ara wọn si meji: nigbati Barnaba si mu Marku, o ba ti ọkọ̀ lọ si Kipru; 40Ṣugbọn Paulu yàn Sila, o si lọ, bi a ti fi i lé ore-ọfẹ Oluwa lọwọ lati ọdọ awọn arakunrin. 41O si là Siria on Kilikia lọ, o nmu ijọ li ọkàn le.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\