EFESU 6

1ẸNYIN ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́. 2Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri), 3Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye. 4Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mã tọ́ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa. 5Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mã gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwarìri, ni otitọ ọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi; 6Ki iṣe ti arojuṣe bi awọn ti nwù enia; ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ mã ṣe ifẹ Ọlọrun lati inu wá; 7Ẹ mã fi inu rere sin bi si Oluwa, kì si iṣe si enia: 8Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira. 9Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀. 10Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀. 11Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu. 12Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun. 13Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro. 14Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra; 15Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ̀ ẹsẹ nyin ni bàta; 16Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì. 17Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmí, ti iṣe ọ̀rọ Ọlọrun: 18Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́; 19Ati fun mi, ki a le fi ohùn fun mi, ki emi ki o le mã fi igboiya yà ẹnu mi, lati mã fi ohun ijinlẹ ihinrere hàn, 20Nitori eyiti emi jẹ ikọ̀ ninu ẹ̀wọn: ki emi ki o le mã fi igboiya sọ̀rọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ. 21Ṣugbọn ki ẹnyin pẹlu ki o le mọ̀ bi nkan ti ri fun mi, bi mo ti nṣe si, Tikiku arakunrin olufẹ ati iranṣẹ olõtọ ninu Oluwa, yio sọ ohun gbogbo di mimọ̀ fun nyin: 22Ẹniti mo rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹ le mọ bi a ti wà, ki on ki o le tu ọkàn nyin ninu. 23Alafia fun awọn ará, ati ifẹ pẹlu igbagbọ́, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Oluwa Jesu Kristi. 24Ki ore-ọfẹ wà pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ Oluwa wa Jesu Kristi li aiṣẹ̀tan.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\