GALATIA 5

1NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú mọ́. 2Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun. 3Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́. 4A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ. 5Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. 6Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ. 7Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ? 8Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá. 9Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu. 10Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ. 11Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. 12Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro. 13Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin. 14Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. 15Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run. 16Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ. 17Nitoriti ara nṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmí, ati Ẹmí lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ má ba le ṣe ohun ti ẹnyin nfẹ. 18Ṣugbọn bi a ba nti ọwọ Ẹmí ṣamọna nyin, ẹnyin kò si labẹ ofin. 19Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahàn, ti iṣe wọnyi; panṣaga, àgbere, ìwa-ẽri, wọ̀bia, 20Ibọriṣa, oṣó, irira, ìja, ilara, ibinu, asọ, ìṣọtẹ, adamọ̀, 21Arankàn, ipania, imutipara, iréde-oru, ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ rí pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun. 22Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́, 23Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni. 24Awọn ti iṣe ti Kristi Jesu ti kàn ara mọ agbelebu ti on ti ifẹ ati ifẹkufẹ rẹ̀. 25Bi awa ba wà lãye sipa ti Ẹmí, ẹ jẹ ki a si mã rìn nipa ti Ẹmí. 26Ẹ máṣe jẹ ki a mã ṣogo-asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\