GALATIA 6

1ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu. 2Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ. 3Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ. 4Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. 5Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀. 6Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni. 7Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká. 8Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun. 9Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀. 10Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́. 11Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin. 12Iye awọn ti nfẹ ṣe aṣehan li ara, nwọn nrọ̀ nyin lati kọla; kiki nitoripe ki a ma ba ṣe inunibini si wọn nitori agbelebu Kristi. 13Nitori awọn ti a kọ nilà pãpã kò pa ofin mọ́, ṣugbọn nwọn nfẹ mu nyin kọla, ki nwọn ki o le mã ṣogo ninu ara nyin. 14Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye. 15Nitoripe ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla, bikoṣe ẹda titun. 16Iye awọn ti o si nrìn gẹgẹ bi ìwọn yi, alafia lori wọn ati ãnu, ati lori Israeli Ọlọrun. 17Lati isisiyi lọ, ki ẹnikẹni máṣe yọ mi lẹnu mọ́: nitori emi nrù àpá Jesu Oluwa kiri li ara mi. 18Ará, ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\