HEBERU 2

1NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan. 2Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́; 3Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́; 4Ọlọrun si nfi iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu, ati onirũru iṣẹ agbara, ati ẹ̀bun Ẹmí Mimọ́ bá wọn jẹri gẹgẹ bí ifẹ rẹ̀? 5Nitoripe ki iṣe abẹ awọn angẹli li o fi aiye ti mbọ̀ ti awa nsọrọ rẹ̀ si. 6Ṣugbọn ẹnikan sọ nibikan wipe, Kili enia ti o fi nṣe iranti rẹ̀, tabi ọmọ enia, ti o mbẹ̀ ẹ wò? 7Iwọ dá a rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ; iwọ fi ogo ati ọlá dé e li ade, iwọ si fi i jẹ olori iṣẹ ọwọ́ rẹ: 8Iwọ fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Nitori niti pe o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ kò kù ohun kan ti kò fi sabẹ rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi awa kò iti ri pe a fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀. 9Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun. 10Nitoripe o yẹ fun u, nitori ẹniti ohun gbogbo ṣe wà, ati nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ni mimu awọn ọmọ pupọ̀ wá sinu ogo, lati ṣe balogun igbala wọn li aṣepé nipa ìjiya. 11Nitori ati ẹniti nsọni di mimọ́ ati awọn ti a nsọ di mimọ́, lati ọdọ ẹnikanṣoṣo ni gbogbo wọn: nitori eyiti ko ṣe tiju lati pè wọn ni arakunrin, 12Wipe, Emi ó sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li ãrin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ. 13Ati pẹlu, Emi o gbẹkẹ̀ mi le e. Ati pẹlu, Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Ọlọrun fifun mi. 14Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu; 15Ki o si le gbà gbogbo awọn ti o ti itori ibẹru iku wà labẹ ìde lọjọ aiye wọn gbogbo. 16Nitoripe, nitõtọ ki iṣe awọn angẹli li o ṣe iranlọwọ fun, ṣugbọn irú-ọmọ Abrahamu li o ṣe iranlọwọ fun. 17Nitorina o yẹ pe ninu ohun gbogbo ki o dabi awọn ará rẹ̀, ki o le jẹ alãnu ati olõtọ Olori Alufa ninu ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le ṣe etutu fun ẹ̀ṣẹ awọn enia. 18Nitori niwọnbi on tikararẹ̀ ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndan wo lọwọ.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\