JOHANU 15

1EMI ni àjara tõtọ, Baba mi si ni oluṣọgba. 2Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹka ti o ba si so eso, on a wẹ̀ ẹ mọ́, ki o le so eso si i. 3Ẹnyin mọ́ nisisiyi nitori ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin. 4Ẹ mã gbé inu mi, emi o si mã gbé inu nyin. Gẹgẹ bi ẹka kò ti le so eso fun ara rẹ̀, bikoṣepe o ba ngbé inu àjara, bẹ̃li ẹnyin, bikoṣepe ẹ ba ngbé inu mi. 5Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan. 6Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna. 7Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin. 8Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi. 9Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹ̃li emi si fẹ nyin: ẹ duro ninu ifẹ mi. 10Bi ẹnyin ba pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi; gẹgẹ bi emi ti pa ofin Baba mi mọ́, ti mo si duro ninu ifẹ rẹ̀. 11Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ̀ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ̀ nyin ki o le kún. 12Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin. 13Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọrẹ́ rẹ̀. 14Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin. 15Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin. 16Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin. 17Nkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun nyin pe, ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin. 18Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ̀ pe, o ti korira mi ṣaju nyin. 19Ibaṣepe ẹnyin iṣe ti aiye, aiye iba fẹ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitoriti ẹnyin kì iṣe ti aiye, ṣugbọn emi ti yàn nyin kuro ninu aiye, nitori eyi li aiye ṣe korira nyin. 20Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu. 21Ṣugbọn gbogbo nkan wọnyi ni nwọn o ṣe si nyin, nitori orukọ mi, nitoriti nwọn kò mọ̀ ẹniti o rán mi. 22Ibaṣepe emi kò ti wá ki n si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun ẹ̀ṣẹ wọn. 23Ẹniti o ba korira mi, o korira Baba mi pẹlu. 24Ibaṣepe emi kò ti ṣe iṣẹ wọnni larin wọn, ti ẹlomiran kò ṣe ri, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn ti ri, nwọn si korira ati emi ati Baba mi. 25Ṣugbọn eyi ṣe ki ọ̀rọ ti a kọ ninu ofin wọn ki o le ṣẹ pe, Nwọn korira mi li ainidi. 26Ṣugbọn nigbati Olutunu na ba de, ẹniti emi ó rán si nyin lati ọdọ Baba wá, ani Ẹmi otitọ nì, ti nti ọdọ Baba wá, on na ni yio jẹri mi: 27Ẹnyin pẹlu yio si jẹri mi, nitoriti ẹnyin ti wà pẹlu mi lati ipilẹṣẹ wá.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\