LUKU 12

1O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe. 2Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀. 3Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀. 4Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́. 5Ṣugbọn emi o si sọ ẹniti ẹnyin o bẹ̀ru fun nyin: Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pani tan, lati wọ́ni lọ si ọrun apadi; lõtọ ni mo wi fun nyin, On ni ki ẹ bẹru. 6Ologoṣẹ marun ki a ntà li owo idẹ wẹ́wẹ meji? a kò si gbagbé ọkan ninu wọn niwaju Ọlọrun? 7Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ki ẹ máṣe bẹ̀ru: ẹnyin ni iye lori jù ologoṣẹ pipọ lọ. 8Mo si wi fun nyin pẹlu, Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, Ọmọ-ẹnia yio si jẹwọ rẹ̀ niwaju awọn angẹli Ọlọrun: 9Ṣugbọn ẹniti o ba sẹ́ mi niwaju enia, a o sẹ́ ẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun. 10Ati ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ-òdi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a kì yio dari rẹ̀ jì i. 11Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi: 12Nitori Ẹmí Mimọ́ yio kọ́ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi. 13Ọkan ninu awujọ si wi fun u pe, Olukọni, sọ fun arakunrin mi ki o pín mi li ogún. 14O si wi fun u pe, Ọkunrin yi, tali o fi mi jẹ onidajọ tabi olùpín-ogún wá fun nyin? 15O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni. 16O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ: 17O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si? 18O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si. 19Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀. 20Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ? 21Bẹ̃ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti ko si li ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun. 22O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora. 23Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ. 24Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? 25Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? 26Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? 27Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. 28Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? 29Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. 30Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. 31Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin. 32Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin. 33Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ. 34Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu. 35Ẹ di amure nyin, ki fitila nyin ki o si mã jo: 36Ki ẹnyin tikara nyin ki o dabi ẹniti nreti oluwa wọn, nigbati on o pada ti ibi iyawo de; pe, nigbati o ba de, ti o si kànkun, ki nwọn ki o le ṣí i silẹ fun u lọgan. 37Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yio ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rẹ̀ li amure, yio si mu wọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn. 38Bi o ba si de nigba iṣọ keji, tabi ti o si de nigba iṣọ kẹta, ti o si ba wọn bẹ̃, ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni. 39Ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati ti olè yio wá, on iba ma ṣọna, kì ba ti jẹ ki a lu ile on já. 40Nitorina ki ẹnyin ki o mura pẹlu: Nitori Ọmọ-enia mbọ̀ ni wakati ti ẹnyin kò daba. 41Peteru si wipe, Oluwa, iwọ pa owe yi fun wa, tabi fun gbogbo enia? 42Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò? 43Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃. 44Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni. 45Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara; 46Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́. 47Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ. 48Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i. 49Iná li emi wá lati fọ̀n si aiye; kili emi si nfẹ bi a ba ti da a ná? 50Ṣugbọn emi ni baptismu kan ti a o fi baptisi mi; ara ti ń ni mi to titi yio fi pari! 51Ẹnyin ṣebi alafia li emi wá fi si aiye? mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ; ki a sá kuku pe iyapa: 52Nitori lati isisiyi lọ, enia marun yio wà ni ile kanna ti a o yà ni ipa, mẹta si meji, ati meji si mẹta. 53A o yà baba ni ipa si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọkunrin si baba; iya si ọmọbinrin rẹ̀, ati ọmọbinrin si iya rẹ̀; iyakọ si iyawo rẹ̀, ati iyawo si iyako rẹ̀. 54O si wi fun ijọ enia pẹlu pe, Nigbati ẹnyin ba ri awọsanma ti o ṣú ni ìha ìwọ-õrùn, ọgan ẹnyin a ni, Ọwara òjo mbọ̀; a si ri bẹ̃. 55Nigbati afẹfẹ gusù ba nfẹ, ẹnyin a ni, Õru yio mu; a si ṣẹ. 56Ẹnyin agabagebe, ẹnyin le moye oju ọrun ati ti aiye; ẽhatiṣe ti ẹnyin kò le mọ̀ akokò yi? 57Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin tikara nyin ko fi rò ohun ti o tọ́? 58Nigbati iwọ ba mbá ọtá rẹ lọ sọdọ olóri, mura li ọ̀na ki a le gbà ọ lọwọ rẹ̀; ki o máṣe fi ọ le onidajọ lọwọ, ki onidajọ máṣe fi ọ le ẹṣọ lọwọ, on a si tì ọ sinu tubu. 59Ki emi ki o wi fun ọ, iwọ ki yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\