LUKU 13

1AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn. 2Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni? 3Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. 4Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ? 5Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. 6O si pa owe yi fun wọn pe: Ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan. 7O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu? 8O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i: 9Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulẹ̀. 10O si nkọ́ni ninu sinagogu kan li ọjọ isimi. 11Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe. 12Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ. 13O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo. 14Olori sinagogu si kun fun irunu, nitoriti Jesu muni larada li ọjọ isimi, o si wi fun ijọ enia pe, Ijọ mẹfa ni mbẹ ti a fi iṣiṣẹ: ninu wọn ni ki ẹnyin ki o wá ki a ṣe dida ara nyin, ki o máṣe li ọjọ isimi. 15Nigbana li Oluwa dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnyin agabagebe, olukuluku nyin ki itú malu tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ kuro nibuso, ki si ifà a lọ imu omi li ọjọ isimi? 16Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá? 17Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá. 18O si wipe, Kini ijọba Ọlọrun jọ? kili emi o si fi wé? 19O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀. 20O si tún wipe, Kili emi iba fi ijọba Ọlọrun wé? 21O dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o fi sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ o fi di wiwu. 22O si nlà arin ilu ati iletò lọ, o nkọ́ni, o si nrìn lọ si iha Jerusalemu. 23Ẹnikan si bi i pe, Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà? O si wi fun wọn pe, 24Ẹ làkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro: nitori mo wi fun nyin, enia pipọ ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, nwọn kì yio si le wọle. 25Nigbati bãle ile ba dide lẹkan fũ, ti o ba si ti sé ilẹkun, ẹnyin o si bẹ̀rẹ si iduro lode, ti ẹ o ma kànkun, wipe, Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa; on o si dahùn wi fun nyin pe, Emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá: 26Nigbana li ẹnyin o bẹ̀rẹ si iwipe, Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọ́ni ni igboro ilu wa. 27On o si wipe, Emi wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ. 28Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ̀, nigbati ẹnyin o ri Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, ati gbogbo awọn woli, ni ijọba Ọlọrun, ti a o si tì ẹnyin sode. 29Nwọn o si ti ìla-õrùn, ati ìwọ-õrùn wá, ati lati ariwa, ati gusù wá, nwọn o si joko ni ijọba Ọlọrun. 30Si wo o, awọn ẹni-ẹ̀hin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ, ti yio di ẹni-ẹ̀hin. 31Ni wakati kanna diẹ ninu awọn Farisi tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Jade, ki iwọ ki o si lọ kuro nihinyi: nitori Herodu nfẹ pa ọ. 32O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ki ẹnyin si sọ fun kọ̀lọkọlọ nì pe, Kiyesi i, emi nlé awọn ẹmi èṣu jade, emi nṣe dida ara loni ati lọla, ati ni ijọ kẹta emi o ṣe aṣepe. 33Ṣugbọn emi kò jẹ má rìn loni, ati lọla, ati li ọtunla: kò le jẹ bẹ̃ pe woli ṣegbé lẹhin odi Jerusalemu. 34Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn woli, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa; nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ́ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! 35Sawõ, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro: lõtọ ni mo si wi fun nyin, Ẹnyin ki yio ri mi, titi yio fi di akoko ti ẹnyin o wipe, Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\