LUKU 14

1O si ṣe, nigbati o wọ̀ ile ọkan ninu awọn olori Farisi lọ li ọjọ isimi lati jẹun, nwọn si nṣọ ọ. 2Si kiyesi i, ọkunrin kan ti o li asunkun mbẹ niwaju rẹ̀. 3Jesu si dahùn o wi fun awọn amofin ati awọn Farisi pe, O ha tọ́ lati mu-ni larada li ọjọ isimi, tabi kò tọ? 4Nwọn si dakẹ. O si mu u, o mu u larada, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ; 5O si dahùn o wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti kẹtẹkẹtẹ tabi malu rẹ̀ yio bọ sinu ihò, ti kì yio si fà a soke lojukanna li ọjọ isimi? 6Nwọn kò si le da a li ohùn mọ́ si nkan wọnyi. 7O si pa owe kan fun awọn ti a pè wá jẹun, nigbati o wò bi nwọn ti nyàn ipò ọlá; o si wi fun wọn pe, 8Nigbati ẹnikan ba pè ọ wá si ibi iyawo, máṣe joko ni ipò ọlá; ki o ma ba jẹ pe, a pè ẹniti o li ọlá jù ọ lọ. 9Nigbati ẹniti o pè ọ ati on ba de, a si wi fun ọ pe, Fun ọkunrin yi li àye; iwọ a si wa fi itiju mu ipò ẹhin. 10Ṣugbọn nigbati a ba pè ọ, lọ ki o si joko ni ipò ẹhin; nigbati ẹniti o pè ọ ba de, ki o le wi fun ọ pe, Ọrẹ́, bọ́ soke: nigbana ni iwọ o ni iyin li oju awọn ti o ba ọ joko ti onjẹ. 11Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, li a o si gbéga. 12Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ. 13Ṣugbọn nigbati iwọ ba se àse, pè awọn talakà, awọn alabùkù arùn, awọn amukun, ati awọn afọju: 14Iwọ o si jẹ alabukun fun; nitori nwọn kò ni ohun ti nwọn o fi san a fun ọ: ṣugbọn a o san a fun ọ li ajinde awọn olõtọ. 15Nigbati ọkan ninu awọn ti o ba a joko tì onjẹ gbọ́ nkan wọnyi, o wi fun u pe, Ibukun ni fun ẹniti yio jẹun ni ijọba Ọlọrun. 16Ṣugbọn o wi fun u pe, Ọkunrin kan se àse-alẹ nla, o si pè enia pipọ: 17O si rán ọmọ-odọ rẹ̀ ni wakati àse-alẹ lati sọ fun awọn ti a ti pè wipe, Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan. 18Gbogbo wọn so bẹ̀rẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi. Ekini wi fun u pe, Mo rà ilẹ kan, emi kò si le ṣe ki ng má lọ iwò o: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi. 19Ekeji si wipe, Mo rà ajaga malu marun, mo si nlọ idán wọn wò: mo bẹ̀ ọ ṣe gafara fun mi. 20Ẹkẹta si wipe, Mo gbeyawo, nitorina li emi kò fi le wá. 21Ọmọ-ọdọ na si pada de, o sọ nkan wọnyi fun oluwa rẹ̀. Nigbana ni bãle ile binu, o wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Jade lọ si igboro, ati si abuja ọ̀na, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amukun, ati awọn afọju wá si ihinyi. 22Ọmọ-ọdọ na si wipe, Oluwa, a ti ṣe bi o ti paṣẹ, àye si mbẹ sibẹ. 23Oluwa na si wi fun ọmọ-ọdọ na pe, Jade lọ si opópo, ati si ọ̀na ọgbà, ki o si rọ̀ wọn lati wọle wá, ki ile mi le kún. 24Nitori mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pè, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi. 25Awọn ọpọ ijọ enia mba a lọ: o si yipada, o si wi fun wọn pe, 26Bi ẹnikan ba tọ̀ mi wá, ti ko si korira baba rẹ̀, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabinrin, ani ati ẹmí ara rẹ̀ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi. 27Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ̀, ki o si ma tọ̀ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi. 28Nitori tani ninu nyin ti npete ati kọ́ ile-iṣọ, ti kì yio kọ́ joko ki o ṣiro iye owo rẹ̀, bi on ni to ti yio fi pari rẹ̀. 29Ki o ma ba jẹ pe nigbati o ba fi ipilẹ ile sọlẹ tan, ti kò le pari rẹ̀ mọ́, gbogbo awọn ti o ri i a bẹ̀rẹ si ifi i ṣe ẹlẹyà, 30Wipe, ọkunrin yi bẹ̀rẹ si ile ikọ́, kò si le pari rẹ̀. 31Tabi ọba wo ni nlọ ibá ọba miran jà, ti kì yio kọ́ joko, ki o si gbèro bi yio le fi ẹgbarun padegun ẹniti nmu ẹgbawa bọ̀ wá kò on loju? 32Bi bẹ̃kọ nigbati onitọhun si wà li òkere, on a ran ikọ si i, a si bere ipinhùn alafia. 33Gẹgẹ bẹ̃ni, ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin, ti kò ba kò ohun gbogbo ti o ni silẹ, kọ̀ le ṣe ọmọ-ẹhin mi. 34Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kili a o fi mu u dùn? 35Kò yẹ fun ilẹ, bẽni kò yẹ fun àtan; bikoṣepe ki a kó o danù. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́ ki o gbọ́.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\