LUKU 5

1O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti, 2O ri ọkọ̀ meji ti nwọn gún leti adagun: ṣugbọn awọn apẹja sọkalẹ kuro ninu wọn, nwọn nfọ̀ àwọn wọn. 3O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na. 4Bi o si ti dakẹ ọ̀rọ isọ, o wi fun Simoni pe, Tì si ibu, ki o si jù àwọn nyin si isalẹ fun akopọ̀. 5Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ. 6Nigbati nwọn si ti ṣe eyi, nwọn kó ọpọlọpọ ẹja: àwọn wọn si ya. 7Nwọn si ṣapẹrẹ si ẹgbẹ wọn, ti o wà li ọkọ̀ keji, ki nwọn ki o wá ràn wọn lọwọ. Nwọn si wá, nwọn si kún ọkọ̀ mejeji, bẹ̃ni nwọn bẹ̀rẹ si irì. 8Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa. 9Hà si ṣe e, ati gbogbo awọn ti mbẹ pẹlu rẹ̀, fun akopọ̀ ẹja ti nwọn kó: 10Bẹ̃ ni Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede, ti nṣe olupẹja pọ pẹlu Simoni. Jesu si wi fun Simoni pe, Má bẹ̀ru; lati isisiyi lọ iwọ o ma mú enia. 11Nigbati nwọn si ti mu ọkọ̀ wọn de ilẹ, nwọn fi gbogbo rẹ̀ silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin lọ. 12O si ṣe, nigbati o wọ̀ ilu kan, kiyesi i, ọkunrin kan ti ẹ̀tẹ bò: nigbati o ri Jesu, o wolẹ, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. 13O si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi kàn a, o ni, Mo fẹ: iwọ di mimọ́. Lọgan ẹ̀tẹ si fi i silẹ lọ. 14O si kílọ fun u pe, ki o máṣe sọ fun ẹnikan: ṣugbọn ki o lọ, ki o si fi ara rẹ hàn fun alufa, ki o si ta ọrẹ fun iwẹnumọ́ rẹ, gẹgẹ bi Mose ti paṣẹ fun ẹrí si wọn. 15Ṣugbọn si iwaju li okikí rẹ̀ nkàn kalẹ: ọ̀pọ ijọ enia si jumọ pade lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara lọdọ rẹ̀ kuro lọwọ ailera wọn. 16O si yẹra si ijù, o si gbadura. 17O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada. 18Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀. 19Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu. 20Nigbati o si ri igbagbọ́ wọn, o wi fun u pe, Ọkunrin yi, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. 21Awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si igberò, wipe, Tali eleyi ti nsọ ọrọ-odi? Tali o le dari ẹ̀ṣẹ jìni bikoṣe Ọlọrun nikanṣoṣo? 22Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin? 23Ewo li o ya jù, lati wipe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide ki iwọ ki o si mã rìn? 24Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si lọ si ile rẹ. 25O si dide lọgan niwaju wọn, o gbé ohun ti o dubulẹ le, o si lọ si ile rẹ̀, o nyìn Ọlọrun logo. 26Ẹnu si yà gbogbo wọn, nwọn si nyìn Ọlọrun logo, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwipe, Awa ri ohun abàmi loni. 27Lẹhin nkan wọnyi o jade lọ, o si ri agbowode kan ti a npè ni Lefi, o joko ni bode: o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. 28O si fi gbogbo nkan silẹ, o dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin. 29Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko. 30Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu. 31Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn dá kò wá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da. 32Emi kò wá ipè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada. 33Nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu fi ngbàwẹ nigbakugba, ti nwọn a si ma gbadura, gẹgẹ bẹ̃ si ni awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi; ṣugbọn awọn tirẹ njẹ, nwọn nmu? 34O si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? 35Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o si gbàwẹ ni ijọ wọnni. 36O si pa owe kan fun wọn pẹlu pe, Kò si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbo ẹ̀wu; bikoṣepe titun fà a ya, ati pẹlu idãsà titun kò si ba ogbologbo aṣọ rẹ. 37Kò si si ẹniti ifi ọti-waini titun sinu ogbologbo ìgo; bikoṣepe ọti-waini titun bẹ́ ìgo na, a si danù, ìgo a si bajẹ. 38Ṣugbọn ọti-waini titun li a ifi sinu igo titun; awọn mejeji a si ṣe dede. 39Kò si si ẹniti imu ìsà ọti-waini tan, ti o si fẹ titun lojukanna: nitoriti o ni, ìsà san jù.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\