MAKU 12

1O si bẹ̀rẹ si ifi owe ba wọn sọ̀rọ pe, Ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si ṣọgba yi i ká, o si wà ibi ifunti waini, o si kọ́ ile-isọ si i, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si àjo. 2Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn oluṣọgba na, ki o le gbà ninu eso ọgba ajara na lọwọ awọn oluṣọgba. 3Nwọn si mu u, nwọn lù u, nwọn si rán a pada lọwọ̀ ofo. 4O si tún rán ọmọ-ọdọ miran si wọn, on ni nwọn si sọ okuta lù, nwọn sá a logbẹ́ li ori, nwọn si ran a lọ ni itiju. 5O si tún rán omiran; eyini ni nwọn si pa: ati ọ̀pọ miran, nwọn lù miran, nwọn si pa miran. 6Ṣugbọn o kù ọmọ rẹ̀ kan ti o ni, ti iṣe ayanfẹ rẹ̀, o si rán a si wọn pẹlu nikẹhin, o wipe, Nwọn ó ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. 7Ṣugbọn awọn oluṣọgba wọnni wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ogún rẹ̀ yio si jẹ tiwa. 8Nwọn si mu u, nwọn pa a, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu ọgba ajara na. 9Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe? On o wá, yio si pa awọn oluṣọgba wọnni run, yio si fi ọgba ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn ẹlomiran. 10Ẹnyin kò ha ti kà iwe-mimọ yi; Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ on na li o di pàtaki igun ile: 11Eyi ni ìṣe Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? 12Nwọn si nwá ọ̀na ati mu u, sugbọn nwọn si bẹ̀ru ijọ enia: nitori nwọn mọ̀ pe, awọn li o powe na mọ: nwọn si fi i silẹ, nwọn lọ. 13Nwọn si rán awọn kan si i ninu awọn Farisi, ati ninu awọn ọmọ-ẹhin Herodu, lati fi ọ̀rọ rẹ̀ mu u. 14Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́? 15Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u? Ṣugbọn Jesu mọ̀ agabagebe wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò? ẹ mu owo-idẹ kan fun mi wá ki emi ki o wò o. 16Nwọn si mu u wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn si wi fun u pe, Ti Kesari ni. 17Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Ẹnu si yà wọn si i gidigidi. 18Awọn Sadusi si tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si; nwọn si bi i lẽre, wipe, 19Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, ti o ba si fi aya silẹ, ti kò si fi ọmọ silẹ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o si gbe iru-ọmọ dide fun arakunrin rẹ̀. 20Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: eyi ekini si gbé iyawo, o si kú lai fi ọmọ silẹ. 21Eyi ekeji si ṣu u lopó, on si kú, bẹ̃li on kò si fi ọmọ silẹ: gẹgẹ bẹ̃ si li ẹkẹta. 22Awọn mejeje si ṣu u lopó, nwọn kò si fi ọmọ silẹ: nikẹhin gbogbo wọn obinrin na kú pẹlu. 23Njẹ li ajinde, nigbati nwọn ba jinde, aya tani yio ha ṣe ninu wọn? awọn mejeje li o sá ni i li aya? 24Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ki ha ṣe nitori eyi li ẹ ṣe ṣina, pe ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ, tabi agbara Ọlọrun? 25Nitori nigbati nwọn o jinde kuro ninu okú, nwọn kò ni gbeyawo, bẹ̃ni nwọn kì yio sinni ni iyawo; ṣugbọn nwọn ó dabi awọn angẹli ti mbẹ li ọrun. 26Ati niti awọn okú pe a o ji wọn dide: ẹnyin ko ti kà a ninu iwe Mose, bi Ọlọrun ti sọ fun u ninu igbẹ́, wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? 27On kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe Ọlọrun awọn alãye: nitorina ẹnyin ṣìna gidigidi. 28Ọkan ninu awọn akọwe tọ̀ ọ wá, nigbati o si gbọ́ bi nwọn ti mbi ara wọn li ere ọ̀rọ, ti o si woye pe, o da wọn lohùn rere, o bi i pe, Ewo li ekini ninu gbogbo ofin? 29Jesu si da a lohùn, wipe, Ekini ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli; Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. 30Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: eyi li ofin ekini. 31Ekeji si dabi rẹ̀, Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ko si si ofin miran, ti o tobi jù wọnyi lọ. 32Akọwe na si wi fun u pe, Olukọni, o dara, otitọ li o sọ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; ko si si omiran bikoṣe on: 33Ati ki a fi gbogbo àiya, ati gbogbo òye, ati gbogbo ọkàn, ati gbogbo agbara fẹ ẹ, ati ki a fẹ ọmọnikeji ẹni bi ara-ẹni, o jù gbogbo ẹbọ-sisun ati ẹbọ lọ. 34Nigbati Jesu ri i pe o fi òye dahùn, o wi fun u pe, Iwọ kò jìna si ijọba Ọlọrun. Lẹhin eyini, kò si ẹnikan ti o jẹ bi i lẽre ohunkan mọ́. 35Bi Jesu si ti nkọ́ni ni tẹmpili, o dahùn wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi iṣe? 36Nitori Dafidi tikararẹ̀ wi nipa Ẹmi Mimọ́ pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. 37Njẹ bi Dafidi tikararẹ̀ ba pè e li Oluwa; nibo li o si ti wa ijẹ ọmọ rẹ̀? Ọpọ ijọ enia si fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. 38O si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikíni li ọjà, 39Ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi ase; 40Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gigun fun aṣehàn: awọn wọnyi ni yio jẹbi pọ̀ju. 41Jesu si joko kọjusi apoti iṣura, o si nwò bi ijọ enia ti nsọ owo sinu apoti iṣura: ọ̀pọ awọn ọlọrọ̀ si sọ pipọ si i. 42Talakà opó kan si wá, o sọ owo idẹ wẹ́wẹ meji ti iṣe idameji owo-bàba kan sinu rẹ̀. 43O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Talakà opó yi sọ sinu apoti iṣura jù gbogbo awọn ti o sọ sinu rẹ̀ lọ. 44Nitori gbogbo nwọn sọ sinu rẹ̀ ninu ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rẹ̀ o sọ ohun gbogbo ti o ni si i, ani gbogbo ini rẹ̀.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\