MAKU 6

1O SI jade nibẹ̀, o wá si ilu on tikararẹ̀; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. 2Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? 3Gbẹnagbẹna na kọ yi, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Jose, ati ti Juda, ati Simoni? awọn arabinrin rẹ̀ kò ha si wà nihinyi lọdọ wa? Nwọn si kọsẹ̀ lara rẹ̀. 4Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀. 5On ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ̀, jù pe o gbé ọwọ́ rẹ̀ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada. 6Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni. 7O si pè awọn mejila na sọdọ rẹ̀, o bẹ̀rẹ si irán wọn lọ ni meji-meji; o si fi aṣẹ fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́; 8O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe mu ohunkohun, lọ si àjo wọn, bikoṣe ọpá nikan; ki nwọn ki o máṣe mu àpo, tabi akara, tabi owo ninu asuwọn wọn: 9Ṣugbọn ki nwọn ki o wọ̀ salubàta: ki nwọn máṣe wọ̀ ẹ̀wu meji. 10O si wi fun wọn pe, Nibikibi ti ẹnyin ba wọ̀ ile kan, nibẹ̀ ni ki ẹ mã gbé titi ẹnyin o fi jade kuro nibẹ̀ na. 11Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọrọ̀ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro nibẹ̀, ẹ gbọ̀n eruku ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu nla na lọ. 12Nwọn si jade lọ, nwọn si wasu ki awọn enia ki o le ronupiwada. 13Nwọn si lé ọ̀pọ awọn ẹmi èṣu jade, nwọn si fi oróro kùn ọ̀pọ awọn ti ara wọn ṣe alaida, nwọn si mu wọn larada. 14Herodu ọba si gburo rẹ̀; (nitoriti okikí orukọ rẹ̀ kàn yiká:) o si wipe, Johanu Baptisti jinde kuro ninu oku, nitorina ni iṣẹ agbara ṣe nṣe lati ọwọ rẹ̀ wá. 15Awọn ẹlomiran wipe, Elijah ni. Ṣugbọn awọn miran wipe, Woli kan ni, tabi bi ọkan ninu awọn woli. 16Ṣugbọn nigbati Herodu gbọ́, o wipe, Johanu ni, ẹniti mo ti bẹ́ lori: on li o jinde kuro ninu okú. 17Herodu tikararẹ̀ sá ti ranṣẹ mu Johanu, o si dè e sinu tubu nitori Herodia, aya Filippi arakunrin rẹ̀: on sá ti fi i ṣe aya. 18Johanu sá ti wi fun Herodu pe, kò tọ́ fun iwọ lati ni aya arakunrin rẹ. 19Nitorina ni Herodia ṣe ni i sinu, on si nfẹ ipa a; ṣugbọn kò le ṣe e: 20Nitori Herodu bẹ̀ru Johanu, o si mọ̀ ọ li olõtọ enia ati ẹni mimọ́, o si ntọju rẹ̀; nigbati o gbọrọ rẹ̀, o ṣe ohun pipọ, o si fi ayọ̀ gbọrọ rẹ̀. 21Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili; 22Nigbati ọmọbinrin Herodia si wọle, ti o si njó, o mu inu Herodu dùn ati awọn ti o ba a joko, ọba si wi fun ọmọbinrin na pe, Bère ohunkohun ti iwọ fẹ lọwọ mi, emi o si fifun ọ. 23O si bura fun u, wipe, Ohunkohun ti iwọ ba bere lọwọ mi, emi o si fifun ọ, titi fi de idameji ijọba mi. 24O si jade lọ, o wi fun iya rẹ̀ pe, Kini ki emi ki o bère? On si wipe, Ori Johanu Baptisti. 25Lojukanna, o si wọle tọ̀ ọba wá kánkan, o bère, wipe, emi nfẹ ki iwọ ki o fi ori Johanu Baptisti fun mi ninu awopọkọ nisisiyi. 26Inu ọba si bajẹ gidigidi; ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati nitori awọn ti o bá a joko pọ̀, kò si fẹ ikọ̀ fun u. 27Lọgan ọba si rán ẹṣọ́ kan, o fi aṣẹ fun u pe, ki o gbé ori rẹ̀ wá: o si lọ, o bẹ́ Johanu lori ninu tubu. 28O si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, o si fi fun ọmọbinrin na: ọmọbinrin na si fi fun iya rẹ̀. 29Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́, nwọn wá, nwọn gbé okú rẹ̀, nwọn si lọ tẹ́ ẹ sinu ibojì. 30Awọn aposteli si kó ara wọn jọ sọdọ Jesu, nwọn si ròhin ohungbogbo ti nwọn ti ṣe fun u, ati ohungbogbo ti nwọn ti kọni. 31O si wi fun wọn pe, Ẹ wá ẹnyin tikaranyin si ibi ijù li apakan, ki ẹ si simi diẹ: nitori ọ̀pọlọpọ li awọn ti nwá ti nwọn si nlọ, nwọn kò tilẹ ri ãye tobẹ̃ ti nwọn iba fi jẹun. 32Nwọn si ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù awọn nikan. 33Awọn enia si ri wọn nigbati nwọn nlọ, ọ̀pọlọpọ si mọ̀ ọ, nwọn si sare ba ti ẹsẹ lọ sibẹ̀ lati ilu nla gbogbo wá, nwọn si ṣiwaju wọn, nwọn si jùmọ wá sọdọ rẹ̀. 34Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ. 35Nigbati ọjọ si bù lọ tan, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si bù lọ tan: 36Rán wọn lọ, ki nwọn ki o le lọ si àgbegbe ilu, ati si iletò ti o yiká, ki nwọn ki o le rà onjẹ fun ara wọn: nitoriti nwọn kò li ohun ti nwọn o jẹ. 37Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa o ha lọ irà akara igba owo idẹ ki a si fifun wọn jẹ? 38O si wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Ẹ lọ wò o. Nigbati nwọn si mọ̀, nwọn wipe, Marun, pẹlu ẹja meji. 39O si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o mu gbogbo wọn joko li ẹgbẹgbẹ lori koriko. 40Nwọn si joko li ẹgbẹgbẹ li ọrọrun ati li aradọta. 41Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn. 42Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó. 43Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu. 44Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin. 45Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká. 46Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura. 47Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ. 48O si ri nwọn nṣiṣẹ ni wiwà ọkọ̀; nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn: nigbati o si di ìwọn iṣọ kẹrin oru, o tọ̀ wọn wá, o nrìn lori okun, on si nfẹ ré wọn kọja. 49Ṣugbọn nigbati nwọn ri ti o nrìn loju omi, nwọn ṣebi iwin ni, nwọn si kigbe soke: 50Nitori gbogbo wọn li o ri i, ti ẹ̀ru si ba wọn. Ṣugbọn lojukanna o si ba wọn sọ̀rọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ tújuka: Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. 51O si wọ̀ inu ọkọ̀ tọ̀ wọn lọ; afẹfẹ si da: ẹ̀ru si ba wọn rekọja gidigidi ninu ara wọn, ẹnu si yà wọn. 52Nwọn kò sá ronu iṣẹ iyanu ti iṣu akara: nitoriti ọkàn wọn le. 53Nigbati nwọn si rekọja tan, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti, nwọn si sunmọ eti ilẹ. 54Bi nwọn si ti njade lati inu ọkọ̀ wá, lojukanna nwọn si mọ̀ ọ, 55Nwọn si sare lọ si gbogbo igberiko yiká, nwọn bẹ̀rẹ si ima gbé awọn ti ara wọn ṣe alaida wá lori akete, si ibiti nwọn gbọ́ pe o wà. 56Nibikibi ti o ba si gbé wọ̀, ni iletò gbogbo, tabi ilu nla, tabi arọko, nwọn ngbé olokunrun kalẹ ni igboro, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, a mu wọn larada.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\