MAKU 9

1O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio tọ́ iku wò, titi nwọn o fi ri ti ijọba Ọlọrun yio fi de pẹlu agbara. 2Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn. 3Aṣọ rẹ̀ si di didán, o si funfun gidigidi; afọṣọ kan li aiye kò le fọ̀ aṣọ fún bi iru rẹ̀. 4Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ. 5Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. 6On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi. 7Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. 8Lojiji, nigbati nwọn si wò yika, nwọn ko si ri ẹnikan mọ́, bikoṣe Jesu nikan pẹlu ara wọn. 9Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, o paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun ti nwọn ri fun ẹnikan, bikoṣe igbati Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú. 10Nwọn si fi ọ̀rọ na pamọ́ sinu ara wọn, nwọn si mbi ara wọn lẽre, kili ajinde kuro ninu okú iba jẹ. 11Nwọn si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Elijah ni yio tètekọ de? 12O si dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ, ni Elijah yio tètekọ, de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò; ati gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ̀ nipa ti Ọmọ-enia pe, ko le ṣaima jìya ohun pipọ, ati pe a o si kọ̀ ọ silẹ. 13Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn si ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i, gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀. 14Nigbati nwọn si de ọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn ri ijọ enia pipọ lọdọ wọn, awọn akọwe si mbi wọn lẽre ọ̀ran. 15Lọgan nigbati gbogbo enia si ri i, ẹnu si yà wọn gidigidi, nwọn si sare tọ ọ nwọn nki i. 16O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn? 17Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá; 18Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e. 19O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi. 20Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu. 21O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? O si wipe, Lati kekere ni. 22Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ. 23Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́. 24Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ. 25Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́. 26On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú. 27Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide. 28Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade? 29O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ. 30Nwọn si ti ibẹ̀ kuro, nwọn si kọja larin Galili; on kò si fẹ ki ẹnikẹni mọ̀. 31Nitori o kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ nwọn o si pa a; lẹhin igbati a ba si pa a tan, yio jinde ni ijọ kẹta. 32Ṣugbọn ọ̀rọ na kò yé wọn, ẹ̀ru si ba wọn lati bi i lẽre. 33O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na? 34Ṣugbọn nwọn dakẹ: nitori nwọn ti mba ara wọn jiyan pe, tali ẹniti o pọ̀ju. 35O si joko, o si pè awọn mejila na, o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba nfẹ ṣe ẹni iwaju, on na ni yio ṣe ẹni ikẹhin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn. 36O si mu ọmọ kekere kan, o fi i sarin wọn; nigbati o si gbé e si apa rẹ̀, o wi fun wọn pe, 37Ẹnikẹni ti o ba gbà ọkan ninu iru awọn ọmọ kekere wọnyi li orukọ mi, o gbà mi: ẹnikẹni ti o ba si gbà mi, ki iṣe emi li o gbà, ṣugbọn o gbà ẹniti o rán mi. 38Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin: 39Jesu si wipe, Ẹ máṣe da a lẹkun mọ́: nitori kò si ẹnikan ti yio ṣe iṣẹ agbara li orukọ mi, ti o si le yara sọ ibi si mi. 40Nitori ẹniti ko ba kọ oju ija si wa, o wà ni iha tiwa. 41Nitori ẹnikẹni ti o ba fi ago omi fun nyin mu li orukọ mi, nitoriti ẹnyin jẹ ti Kristi, lõtọ ni mo wi fun nyin, on kì yio padanù ère rẹ̀ bi o ti wù ki o ri. 42Ẹnikẹni ti o ba si mu ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o sàn fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si sọ ọ sinu omi okun. 43Bi ọwọ́ rẹ, ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ lọ si ibi iye, jù ki o li ọwọ mejeji ki o lọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku, 44Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na kì si ikú. 45Bi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsè, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akesẹ lọ si ibi ìye, jù ki o li ẹsẹ mejeji ki a gbé ọ sọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku, 46Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú. 47Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade: o sàn fun ọ ki o lọ si ijọba Ọlọrun li olojukan, jù ki o li oju mejeji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apadi, 48Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú. 49Nitoripe olukukuku li a o fi iná dùn, ati gbogbo ẹbọ li a o si fi iyọ̀ dùn. 50Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba sọ agbara rẹ̀ nù, kili ẹ o fi mu u dùn? Ẹ ni iyọ̀ ninu ara nyin, ki ẹ si ma wà li alafia lãrin ara nyin.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\