MATIU 12

1LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ. 2Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi. 3O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò ti kà ohun ti Dafidi ṣe, nigbati ebi npa a, ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀: 4Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si jẹ akara ifihàn, eyiti kò tọ́ fun u lati jẹ, ati fun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀, bikoṣe fun kìki awọn alufa? 5Tabi ẹnyin ko ti kà a ninu ofin, bi o ti ṣe pe lọjọ isimi awọn alufa ti o wà ni tẹmpili mbà ọjọ isimi jẹ ti nwọn si wà li aijẹbi? 6Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, ẹniti o jù tẹmpili lọ mbẹ nihin. 7Ṣugbọn ẹnyin iba mọ̀ ohun ti eyi jẹ: Anu li emi nfẹ ki iṣe ẹbọ; ẹnyin kì ba ti dá awọn alailẹṣẹ lẹbi. 8Nitori Ọmọ-enia jẹ́ Oluwa ọjọ isimi. 9Nigbati o si kuro nibẹ̀, o lọ sinu sinagogu wọn. 10Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀. 11O si wi fun wọn pe, Ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke? 12Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ? nitorina li o ṣe tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi. 13Nitorina li o wi fun ọkunrin na pe, Na ọwọ́ rẹ. On si nà a; ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò rẹ̀ gẹgẹ bi ekeji. 14Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a. 15Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada. 16O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn: 17Ki eyi ti a ti ẹnu wolĩ Isaiah wi ki o ba le ṣẹ, pe, 18Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi. 19On kì yio jà, kì yio si kigbe; bẹ̃li ẹnikẹni kì yio gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. 20Iyè fifọ́ ni on kì yio ṣẹ́, owu fitila ti nru ẹ̃fin nì on kì yio si pa, titi yio fi mu idajọ dé iṣẹgun. 21Orukọ rẹ̀ li awọn keferi yio ma gbẹkẹle. 22Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran. 23Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi? 24Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu. 25Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro. 26Bi Satani ba si nlé Satani jade, o yapa si ara rẹ̀; ijọba rẹ̀ yio ha ṣe le duro? 27Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina ni nwọn o fi ma ṣe onidajọ nyin. 28Ṣugbọn bi o ba ṣe pe Ẹmí Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, njẹ ijọba Ọlọrun de ba nyin. 29Tabi ẹnikan yio ti ṣe wọ̀ ile alagbara lọ, ki o si kó o li ẹrù, bikoṣepe o kọ́ dè alagbara na? nigbana ni yio si kó o ni ile. 30Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o nṣe odi si mi; ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfọnka. 31Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia. 32Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀. 33Sọ igi di rere, eso rẹ̀ a si di rere; tabi sọ igi di buburu, eso rẹ̀ a si di buburu: nitori nipa eso li ã fi mọ igi. 34Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ. 35Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá. 36Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ. 37Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi. 38Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe ati Farisi dahùn wipe, Olukọni, awa nwá àmi lọdọ rẹ. 39Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Iran buburu ati iran panṣaga nwá àmi; kò si àmi ti a o fi fun u, bikoṣe àmi Jona wolĩ. 40Nitori bi Jona ti gbé ọsán mẹta ati oru mẹta ninu ẹja; bẹ̃li Ọmọ-enia yio gbé ọsán mẹta on oru mẹta ni inu ilẹ. 41Awọn ara Ninefe yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, nwọn, o si da a lẹbi: nitori nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Jona lọ mbẹ nihinyi. 42Ọbabirin gusù yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, yio si da a lẹbi: nitori o ti ikangun aiye wá igbọ́ ọgbọ́n Solomoni; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi. 43Nigbati ẹmi aimọ́ kan ba jade kuro lara enia, a ma rìn kiri ni ibi gbigbẹ, a ma wá ibi isimi, kì si iri. 44Nigbana ni o wipe, Emi o pada lọ si ile mi, nibiti mo gbé ti jade wá; nigbati o si de, o bá a, o ṣofo, a gbá a mọ́, a si ṣe e li ọṣọ. 45Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu ara rẹ̀, ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn bọ si inu rẹ̀, nwọn si ngbé ibẹ̀; igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri fun iran buburu yi pẹlu. 46Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ. 47Nigbana li ẹnikan wi fun u pe, Wo o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ba ọ sọ̀rọ. 48Ṣugbọn o dahùn o si wi fun ẹniti o sọ fun u pe, Tani iya mi? ati tani awọn arakunrin mi? 49O si nà ọwọ́ rẹ̀ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Ẹ wò iya mi ati awọn arakunrin mi! 50Nitori ẹnikẹni ti o ba nṣe ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\