MATIU 14

1LI akokò na ni Herodu tetrarki gbọ́ okikí Jesu, 2O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀. 3Herodu sá ti mu Johanu, o dè e, o si fi i sinu tubu, nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀. 4Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i. 5Nigbati o si nfẹ pa a, o bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ. 6Ṣugbọn nigbati a nṣe iranti ọjọ ibí Herodu, ọmọbinrin Herodia jó lãrin wọn, inu Herodu si dùn. 7Nitorina li o ṣe fi ibura ṣe ileri lati fun u li ohunkohun ti o ba bère. 8Ẹniti iya rẹ̀ ti kọ́ tẹlẹ ri, o wipe, Fun mi li ori Johanu Baptisti nihinyi ninu awopọkọ. 9Inu ọba si bajẹ: ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati awọn ti o bá a joko tì onjẹ, o ni ki a fi fun u. 10O si ranṣẹ lọ, o bẹ́ Johanu li ori ninu tubu. 11A si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, a si fifun ọmọbinrin na; o si gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ. 12Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wá, nwọn gbé okú rẹ̀ sin, nwọn si lọ, nwọn si wi fun Jesu. 13Nigbati Jesu si gbọ́, o dide kuro nibẹ̀, o ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù, on nikan; nigbati awọn enia si gbọ́, nwọn si ti ilu wọn rìn tọ̀ ọ li ẹsẹ. 14Jesu jade lọ, o ri ọ̀pọlọpọ enia, inu rẹ̀ si yọ́ si wọn, o si ṣe dida arùn ara wọn. 15Nigbati o di aṣalẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si kọja tan: rán ijọ enia lọ, ki nwọn ki o le lọ si iletò lọ irà onjẹ fun ara wọn. 16Jesu si wi fun wọn pe, Nwọn kò ni ilọ; ẹ fun wọn li onjẹ. 17Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun ati ẹja meji nihinyi. 18O si wipe, Ẹ mu wọn fun mi wá nihinyi. 19O si paṣẹ ki ijọ enia joko lori koriko, o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na; nigbati o gbé oju soke ọrun, o sure, o si bù u, o fi akara na fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia. 20Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó; nwọn si ko ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n mejila kún. 21Awọn ti o si jẹ ẹ to ìwọn ẹgbẹ̃dọgbọn ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde. 22Lojukanna Jesu si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o ṣiwaju rẹ̀ lọ si apakeji, nigbati on tú ijọ enia ká. 23Nigbati o si tú ijọ enia ká tan, o gùn ori òke lọ, on nikan, lati gbadura: nigbati alẹ si lẹ, on nikan wà nibẹ̀. 24Ṣugbọn nigbana li ọkọ̀ wà larin adagun, ti irumi ntì i siwa sẹhin: nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn. 25Nigbati o di iṣọ kẹrin oru, Jesu tọ̀ wọn lọ, o nrìn lori okun. 26Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i ti o nrìn lori okun, ẹ̀ru bà wọn, nwọn wipe, Iwin ni; nwọn fi ibẹru kigbe soke. 27Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru. 28Peteru si dá a lohùn, wipe, Oluwa, bi iwọ ba ni, paṣẹ ki emi tọ̀ ọ wá lori omi. 29O si wipe, Wá. Nigbati Peteru sọkalẹ lati inu ọkọ̀ lọ, o rìn loju omi lati tọ̀ Jesu lọ. 30Ṣugbọn nigbati o ri ti afẹfẹ le, ẹru ba a; o si bẹ̀rẹ si irì, o kigbe soke, wipe, Oluwa, gbà mi. 31Lojukanna Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o dì i mu, o si wi fun u pe, Iwọ onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti iwọ fi nṣiyemeji? 32Nigbati nwọn si bọ́ sinu ọkọ̀, afẹfẹ dá. 33Nigbana li awọn ti mbẹ ninu ọkọ̀ wá, nwọn si fi ori balẹ fun u, wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun ni iwọ iṣe. 34Nigbati nwọn si rekọja si apakeji, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti. 35Nigbati awọn enia ibẹ̀ si mọ̀ pe on ni, nwọn ranṣẹ lọ si gbogbo ilu na yiká, nwọn si gbé gbogbo awọn ọlọkunrùn tọ̀ ọ́ wá. 36Nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn gbogbo awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, di alara dida ṣáṣá.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\