MATIU 19

1O si ṣe, nigbati Jesu pari ọ̀rọ wọnyi tan, o kuro ni Galili, o si lọ si ẹkùn Judea li oke odò Jordani. 2Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, o si mu wọn larada nibẹ̀. 3Awọn Farisi si wá sọdọ rẹ̀, nwọn ndán a wò, nwọn si wi fun u pe, O ha tọ́ fun ọkunrin ki o kọ̀ aya rẹ̀ silẹ nitori ọ̀ran gbogbo? 4O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo, 5O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan. 6Nitorina nwọn ki iṣe meji mọ́ bikoṣe ara kan. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn. 7Nwọn wi fun u pe, Ẽṣe ti Mose fi aṣẹ fun wa, wipe, ki a fi iwe ikọsilẹ fun u, ki a si kọ̀ ọ silẹ? 8O wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin ni Mose ṣe jẹ fun nyin lati mã kọ̀ aya nyin silẹ, ṣugbọn lati igba àtetekọṣe wá kò ri bẹ̃. 9Mo si wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣepe nitori àgbere, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. 10Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Bi ọ̀ran ọkunrin ba ri bayi si aya rẹ̀, kò ṣànfani lati gbé iyawo. 11Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Gbogbo enia kò le gbà ọ̀rọ yi, bikoṣe awọn ẹniti a fi bùn. 12Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a. 13Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi. 14Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun. 15O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀. 16Si kiyesi i, ẹnikan tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Olukọni rere, ohun rere kili emi o ṣe, ki emi ki o le ni ìye ainipẹkun? 17O si wi fun u pe, Eṣe ti iwọ fi pè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun: ṣugbọn bi iwọ ba nfẹ wọ̀ ibi ìye, pa ofin mọ́. 18O bi i lẽre pe, Ewo? Jesu wipe, Iwọ kò gbọdọ pa enia; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jale; Iwọ kò gbọdọ jẹri eke; 19Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ. 20Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù? 21Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin. 22Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀. 23Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun. 24Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. 25Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là? 26Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe. 27Nigbana ni Peteru dahùn, o si wi fun u pe, Wò o, awa ti fi gbogbo rẹ̀ silẹ, awa si ntọ̀ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni? 28Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila. 29Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun. 30Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\