MATIU 20

1IJỌBA ọrun sá dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle ile, ti o jade ni kutukutu owurọ lati pè awọn alagbaṣe sinu ọgba ajara rẹ̀. 2Nigbati o si ba awọn alagbaṣe pinnu rẹ̀ si owo idẹ kọkan li õjọ, o rán wọn lọ sinu ọgba ajara rẹ̀. 3O si jade lakokò wakati ẹkẹta ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran, nwọn duro nibi ọja, 4O si wi fun wọn pe; Ẹ lọ si ọgba ajara pẹlu, ohunkohun ti o ba tọ́ emi o fifun nyin. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ sibẹ̀. 5O tún jade lọ lakokò wakati kẹfa ati kẹsan ọjọ, o si ṣe bẹ̃. 6O si jade lọ lakokò wakati kọkanla ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran ti o duro, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe? 7Nwọn wi fun u pe, Nitoriti kò si ẹni ti o fun wa li agbaṣe; O wi fun wọn pe, Ẹ lọ pẹlu sinu ọgba ajara; eyi ti o ba tọ́ li ẹnyin o ri gbà. 8Nigbati o di oju alẹ oluwa ọgba ajara wi fun iriju rẹ̀ pe, Pè awọn alagbaṣe nì, ki o si fi owo agbaṣe wọn fun wọn, bẹ̀rẹ lati ẹni ikẹhin lọ si ti iṣaju. 9Nigbati awọn ti a pè lakokò wakati kọkanla ọjọ de, gbogbo wọn gbà owo idẹ kọkan. 10Ṣugbọn nigbati awọn ti o ti ṣaju de, nwọn ṣebi awọn o gbà jù bẹ̃ lọ; olukuluku wọn si gbà owo idẹ kọkan. 11Nigbati nwọn gbà a tan, nwọn nkùn si bãle na, 12Wipe, Awọn ará ikẹhin wọnyi ṣiṣẹ kìki wakati kan, iwọ si mu wọn bá wa dọgba, awa ti o ti rù ẹrù, ti a si faradà õru ọjọ. 13O si da ọkan ninu wọn lohùn pe, Ọrẹ́, emi ko ṣìṣe si ọ: iwọ ki o ba mi pinnu rẹ̀ si owo idẹ kan li õjọ? 14Gbà eyi ti iṣe tirẹ, ki o si ma ba tirẹ lọ: emi o si fifun ikẹhin yi, gẹgẹ bi mo ti fifun ọ. 15Kò ha tọ́ ki emi ki o fi nkan ti iṣe ti emi ṣe bi o ti wù mi? oju rẹ korò nitoriti emi ṣe ẹni rere? 16Bẹ̃li awọn ikẹhin yio di ti iwaju, awọn ẹni iwaju yio si di ti ikẹhin: nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn. 17Jesu si ngoke lọ si Jerusalemu, o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila si apakan li ọ̀na, o si wi fun wọn pe, 18Wò o, awa ngoke lọ si Jerusalemu; a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ, nwọn o si da a lẹbi ikú. 19Nwọn o si fà a le awọn keferi lọwọ lati fi i ṣe ẹlẹyà, lati nà a, ati lati kàn a mọ agbelebu: ni ijọ kẹta yio si jinde. 20Nigbana ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọn ọmọ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o bẹ̀ ẹ, o si nfẹ ohun kan li ọwọ́ rẹ̀. 21O si bi i pe, Kini iwọ nfẹ? O wi fun u pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ́ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ́ òsi ni ijọba rẹ. 22Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e. 23O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá. 24Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́ ọ, nwọn binu si awọn arakunrin wọn mejeji. 25Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹnyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a ma lò agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. 26Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ̀ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin; 27Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin: 28Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia. 29Bi nwọn ti nti Jeriko jade, ọ̀pọ enia tọ̀ ọ lẹhin. 30Si kiyesi i, awọn ọkunrin afọju meji joko leti ọ̀na, nigbati nwọn gbọ́ pe Jesu nrekọja, nwọn kigbe soke, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. 31Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa. 32Jesu si dẹsẹ duro, o pè wọn, o si wipe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? 33Nwọn wi fun u pe, Oluwa, ki oju wa ki o le là. 34Bẹ̃ni Jesu ṣãnu fun wọn, o si fi ọwọ́ tọ́ wọn li oju: lọgan oju wọn si là, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\