MATIU 21

1NIGBATI nwọn sunmọ eti Jerusalemu, ti nwọn de Betfage li òke Olifi, nigbana ni Jesu rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji lọ. 2O wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin, lọgan ẹnyin o ri kẹtẹkẹtẹ kan ti a so ati ọmọ rẹ̀ pẹlu: ẹ tú wọn, ki ẹ si fà wọn fun mi wá. 3Bi ẹnikẹni ba si wi nkan fun nyin, ẹnyin o wipe, Oluwa ni ifi wọn ṣe; lọgán ni yio si rán wọn wá. 4Gbogbo eyi li a ṣe, ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu wolĩ wá ki o le ṣẹ, pe, 5Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ. 6Awọn ọmọ-ẹhin na si lọ, nwọn ṣe bi Jesu ti wi fun wọn. 7Nwọn si fà kẹtẹkẹtẹ na wá, ati ọmọ rẹ̀, nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹhin wọn, nwọn si gbé Jesu kà a. 8Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na. 9Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun. 10Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi? 11Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili. 12Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. 13O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà. 14Ati awọn afọju ati awọn amukun wá sọdọ rẹ̀ ni tẹmpili; o si mu wọn larada. 15Ṣugbọn nigbati awọn olori alufa ati awọn akọwe ri ohun iyanu ti o ṣe, ati bi awọn ọmọ kekeke ti nke ni tẹmpili, wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi; inu bi wọn gidigidi, 16Nwọn si wi fun u pe, Iwọ gbọ́ eyiti awọn wọnyi nwi? Jesu si wi fun wọn pe, Bẹ̃ni; ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé? 17O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀. 18Nigbati o di owurọ̀, bi o ti npada bọ̀ si Jerusalemu, ebi npa a. 19Nigbati o ri igi ọ̀pọtọ li ọ̀na, o lọ sibẹ̀, kò si ri ohun kan lori rẹ̀, bikoṣe kìki ewé, o si wi fun u pe, Ki eso ki o má so lori rẹ lati oni lọ titi lailai. Lojukanna igi ọpọtọ na gbẹ. 20Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, ẹnu yà wọn, nwọn wipe, Igi ọpọtọ yi mà tete gbẹ? 21Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ. 22Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bère ninu adura pẹlu igbagbọ́, ẹnyin o ri gbà. 23Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi? 24Jesu si dahun o si wi fun wọn pe, Emi ó si bi nyin lẽre ohun kan pẹlu, bi ẹnyin ba sọ fun mi, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi: 25Baptismu Johanu, nibo li o ti wá? lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni, on o wi fun wa pe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́? 26Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; awa mbẹ̀ru ijọ enia, nitori gbogbo wọn kà Johanu si wolĩ. 27Nwọn si da Jesu lohùn, wipe, Awa ko mọ. O si wi fun wọn pe, Njẹ emi kì yio si wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi. 28Ṣugbọn kili ẹnyin nrò? Ọkunrin kan wà ti o li ọmọ ọkunrin meji; o tọ̀ ekini wá, o si wipe, Ọmọ, lọ iṣiṣẹ loni ninu ọgba ajara mi. 29O si dahùn wipe, Emi kì yio lọ: ṣugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ. 30O si tọ̀ ekeji wá, o si wi bẹ̃ gẹgẹ. O si dahùn wi fun u pe, Emi o lọ, baba: kò si lọ. 31Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun. 32Nitori Johanu ba ọ̀na ododo tọ̀ nyin wá, ẹnyin kò si gbà a gbọ́: ṣugbọn awọn agbowode ati awọn panṣaga gbà a gbọ́: ṣugbọn ẹnyin, nigbati ẹnyin si ri i, ẹ kò ronupiwada nikẹhin, ki ẹ le gbà a gbọ́. 33Ẹ gbọ́ owe miran; Bãle ile kan wà ti o gbìn ajara, o si sọgba yi i ká, o wà ibi ifunti sinu rẹ̀, o kọ́ ile-iṣọ, o si fi ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba, o si lọ si ajò. 34Nigbati akokò eso sunmọ etile, o ràn awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si awọn oluṣọgba na, ki nwọn ki o le gbà wá ninu eso rẹ̀. 35Awọn oluṣọgba si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn lù ekini, nwọn pa ekeji, nwọn si sọ ẹkẹta li okuta. 36O si tun rán awọn ọmọ-ọdọ miran ti o jù awọn ti iṣaju lọ: nwọn si ṣe bẹ̃ si wọn gẹgẹ. 37Ṣugbọn ni ikẹhin gbogbo wọn, o rán ọmọ rẹ̀ si wọn, o wipe, Nwọn o ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi. 38Ṣugbọn nigbati awọn oluṣọgba ri ọmọ na, nwọn wi fun ara wọn pe, Eyiyi li arole; ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si kó ogún rẹ̀. 39Nwọn si mu u, nwọn wọ́ ọ jade kuro ninu ọgbà ajara na, nwọn si pa a. 40Njẹ nigbati oluwa ọgbà ajara ba de, kini yio ṣe si awọn oluṣọgba wọnni? 41Nwọn wi fun u pe, Yio pa awọn enia buburu wọnni run ni ipa òṣi, yio si fi ọgbà ajara rẹ̀ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba miran, awọn ti o ma fi eso rẹ̀ fun u lakokò. 42Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a ninu iwe mimọ́ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa? 43Nitorina emi wi fun nyin pe, A o gbà ijọba Ọlọrun lọwọ nyin, a o si fifun orilẹ-ede ti yio ma mu eso rẹ̀ wá. 44Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta yi yio fọ́: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lũlu. 45Nigbati awọn olori alufa ati awọn Farisi gbọ́ owe rẹ̀ nwọn woye pe awọn li o mba wi. 46Ṣugbọn nigbati nwọn nwá ọ̀na ati gbé ọwọ́ le e, nwọn bẹ̀ru ijọ enia, nitoriti nwọn kà a si wolĩ.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\