MATIU 23

1NIGBANA ni Jesu wi fun ijọ enia, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, 2Pe, Awọn akọwe pẹlu awọn Farisi joko ni ipò Mose: 3Nitorina ohunkohun gbogbo ti nwọn ba wipe ki ẹ kiyesi, ẹ mã kiyesi wọn ki ẹ si mã ṣe wọn; ṣugbọn ẹ má ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: nitoriti nwọn a ma wi, ṣugbọn nwọn ki iṣe. 4Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na. 5Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn. 6Nwọn fẹ ipò ọlá ni ibi ase, ati ibujoko ọla ni sinagogu, 7Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi. 8Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin. 9Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun. 10Ki a má si ṣe pè nyin ni olukọni: nitori ọkan li Olukọni nyin, ani Kristi. 11Ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin. 12Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ li a o gbé ga. 13Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle. 14Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin jẹ ile awọn opó run, ati nitori aṣehan, ẹ ngbadura gigun: nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọ̀ju. 15Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ. 16Egbé ni fun nyin, ẹnyin amọ̀na afọju, ti o nwipe, Ẹnikẹni ti o ba fi tẹmpili bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi wura tẹmpili bura, o di ajigbese. 17Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, wura, tabi tẹmpili ti nsọ wura di mimọ́? 18Ati pe, Ẹnikẹni ti o ba fi pẹpẹ bura, kò si nkan; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi ẹ̀bun ti o wà lori rẹ̀ bura, o di ajigbese. 19Ẹnyin alaimoye ati afọju: ewo li o pọ̀ju, ẹ̀bun, tabi pẹpẹ ti nsọ ẹ̀bun di mimọ́? 20Njẹ ẹniti o ba si fi pẹpẹ bura, o fi i bura, ati ohun gbogbo ti o wà lori rẹ̀. 21Ẹniti o ba si fi tẹmpili bura, o fi i bura, ati ẹniti o ngbé inu rẹ̀. 22Ẹniti o ba si fi ọrun bura, o fi itẹ́ Ọlọrun bura, ati ẹniti o joko lori rẹ̀. 23Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin ngbà idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọ̀ran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbọ́: wọnyi li o tọ́ ti ẹnyin iba ṣe, laisi fi iyoku silẹ laiṣe. 24Ẹnyin afọju amọ̀na, ti nsẹ́ kantikanti ti o si ngbé ibakasiẹ mì. 25Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia. 26Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu. 27Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo. 28Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu ẹ kún fun agabagebe ati ẹ̀ṣẹ. 29Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin kọ́ ibojì awọn wolĩ, ẹnyin si ṣe isà okú awọn olododo li ọṣọ, 30Ẹnyin si wipe, Awa iba wà li ọjọ awọn baba wa, awa kì ba li ọwọ́ ninu ẹ̀jẹ awọn wolĩ. 31Njẹ ẹnyin li ẹlẹri fun ara nyin pe, ẹnyin li awọn ọmọ awọn ẹniti o pa awọn wolĩ. 32Njẹ ẹnyin kuku kún òṣuwọn baba nyin de oke. 33Ẹnyin ejò, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi? 34Nitorina ẹ kiyesi i, Emi rán awọn wolĩ, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin ó si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu: 35Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ. 36Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo nkan wọnyi ni yio wá sori iran yi. 37Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! 38Sawò o, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro. 39Mo si wi fun nyin, Ẹnyin kì yio ri mi mọ́ lati isisiyi lọ, titi ẹnyin o fi wipe, Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\