MATIU 26

1O SI ṣe, nigbati Jesu pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, 2Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu. 3Nigbana li awọn olori alufa, awọn akọwe, ati awọn àgba awọn enia pejọ li ãfin olori alufa, ẹniti a npè ni Kaíafa, 4Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a. 5Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia. 6Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, 7Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ. 8Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo? 9A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà. 10Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara. 11Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn ẹnyin kò ni mi nigbagbogbo. 12Nitori li eyi ti obinrin yi dà ororo ikunra yi si mi lara, o ṣe e fun sisinku mi. 13Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a ba gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ pẹlu li a o si ròhin eyi ti obinrin yi ṣe, ni iranti rẹ̀. 14Nigbana li ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Judasi Iskariotu tọ̀ awọn olori alufa lọ, 15O si wipe, Kili ẹnyin o fifun mi, emi o si fi i le nyin lọwọ? Nwọn si ba a ṣe adehùn ọgbọ̀n owo fadaka. 16Lati igba na lọ li o si ti nwá ọ̀na lati fi i le wọn lọwọ. 17Nigba ọjọ ikini ajọ aiwukara, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse silẹ dè ọ lati jẹ irekọja? 18O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi. 19Awọn ọmọ-ẹhin na si ṣe gẹgẹ bi Jesu ti fi aṣẹ fun wọn; nwọn si pèse irekọja silẹ. 20Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila. 21Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. 22Nwọn si kãnu gidigidi, olukuluku wọn bẹ̀rẹ si ibi i lẽre pe, Oluwa, emi ni bi? 23O si dahùn wipe, Ẹniti o bá mi tọwọ bọ inu awo, on na ni yio fi mi hàn. 24Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lati ọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a ko bí i. 25Nigbana ni Judasi, ti o fi i hàn, dahùn wipe, Rabbi, emi ni bi? O si wi fun u pe, Iwọ wi i. 26Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Gbà, jẹ; eyiyi li ara mi. 27O si mu ago, o dupẹ, o si fifun wọn, o wipe, Gbogbo nyin ẹ mu ninu rẹ̀; 28Nitori eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia fun imukuro ẹ̀ṣẹ. 29Ṣugbọn mo wi fun nyin, lati isisiyi lọ emi kì yio mu ninu eso ajara yi mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o si bá nyin mu titun ni ijọba Baba mi. 30Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi. 31Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru yi: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o kọlù oluṣọ-agutan, a o si tú agbo agutan na ká kiri. 32Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili. 33Peteru si dahùn o wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀ lara rẹ, emi kì yio kọsẹ̀ lai. 34Jesu wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, Li oru yi ki akukọ ki o to kọ iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta. 35Peteru wi fun u pe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi kò jẹ sẹ́ ọ. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin wi pẹlu. 36Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi. 37O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì. 38Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na. 39O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ. 40O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan? 41Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara. 42O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu ú, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe. 43O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun. 44O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna. 45Nigbana li o tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: wo o, wakati kù fẹfẹ, ti a o si fi Ọmọ-ẹnia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ. 46Ẹ dide, ki a mã lọ: wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi. 47Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá. 48Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu ko li ẹnu, on na ni: ẹ mú u. 49Lojukanna o wá sọdọ Jesu, o si wipe, Alafia, Olukọni; o si fi ẹnu ko o li ẹnu. 50Jesu si wi fun u pe, Ọrẹ́, nitori kini iwọ fi wá? Nigbana ni nwọn wá, nwọn si gbé ọwọ́ le Jesu, nwọn si mu u. 51Si wo o, ọkan ninu awọn ti o wà pẹlu Jesu nà ọwọ́ rẹ̀, o si fà idà rẹ̀ yọ, o si ṣá ọkan ti iṣe ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke e li etí sọnù. 52Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Fi idà rẹ si ipò rẹ̀: nitoripe gbogbo awọn ti o mu idà ni yio ti ipa idà ṣegbé. 53Iwọ ṣebi emi ko le kepè Baba mi, on iba si fun mi jù legioni angẹli mejila lọ lojukanna yi? 54Ṣugbọn iwe-mimọ́ yio ha ti ṣe ti yio fi ṣẹ, pe bẹ̃ni yio ri? 55Ni wakati na ni Jesu wi fun ijọ enia pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? li ojojumọ li emi mba nyin joko ni tẹmpili ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si gbé ọwọ́ le mi. 56Ṣugbọn gbogbo eyi ṣe, ki iwe-mimọ́ awọn wolĩ ba le ṣẹ. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi i silẹ, nwọn si sá lọ. 57Awọn ti o si mu Jesu, fà a lọ si ile Kaiafa, olori alufa, nibiti awọn akọwe ati awọn agbàgba gbé pejọ si. 58Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ́ lẹhin li òkere titi fi de agbala olori alufa, o bọ́ si ile, o si bá awọn ọmọ-ọdọ na joko lati ri opin rẹ̀. 59Nigbana li olori alufa, ati awọn alàgba, ati gbogbo ajọ igbimọ nwá ẹlẹri eke si Jesu lati pa a; 60Ṣugbọn nwọn ko ri ohun kan: otitọ li ọ̀pọ ẹlẹri eke wá, ṣugbọn nwọn kò ri ohun kan. Nikẹhin li awọn ẹlẹri eke meji wá; 61Nwọn wipe, ọkunrin yi wipe, Emi le wó tẹmpili Ọlọrun, emi o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta. 62Olori alufa si dide, o si wi fun u pe, Iwọ ko dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? 63Ṣugbọn Jesu dakẹ. Olori alufa dahùn o si wi fun u pe, Mo fi Ọlọrun alãye bẹ̀ ọ pé, ki iwọ ki o sọ fun wa bi iwọ ba ṣe Kristi Ọmọ Ọlọrun. 64Jesu wi fun u pe, Iwọ wi i: ṣugbọn mo wi fun nyin, Lẹhin eyi li ẹnyin o ri Ọmọ-enia ti yio joko li ọwọ́ ọtún agbara, ti yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. 65Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, O sọ ọrọ-odi; ẹlẹri kili a si nwá? wo o, ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na nisisiyi. 66Ẹnyin ti rò o si? Nwọn dahùn, wipe, O jẹbi ikú. 67Nigbana ni nwọn tutọ́ si i loju, nwọn kàn a lẹṣẹ́; awọn ẹlomiran fi atẹ́lọwọ́ wọn gbá a loju; 68Nwọn wipe, Sọtẹlẹ fun wa, iwọ, Kristi, tali ẹniti o nlù ọ ni? 69Peteru joko lode li ãfin: nigbana ni ọmọbinrin kan tọ̀ ọ wá, o wipe, Iwọ pẹlu wà pẹlu Jesu ti Galili. 70Ṣugbọn o sẹ́ li oju gbogbo wọn, o wipe, Emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. 71Nigbati o si jade si iloro, ọmọbinrin miran si ri i, o si wi fun awọn ti o wà nibẹ̀ pe, ọkunrin yi wà pẹlu Jesu ti Nasareti. 72O si tun fi èpe sẹ́, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na. 73Nigbati o pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun Peteru pe, Lõtọ ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe; nitoripe ohùn rẹ fi ọ hàn. 74Nigbana li o bẹ̀rẹ si ibura ati si iré, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na. Lojukanna akukọ si kọ. 75Peteru si ranti ọ̀rọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi lẹrinmẹta. O si bọ si ode, o sọkun kikorò.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\