MATIU 27

1NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a: 2Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ. 3Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba. 4O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o. 5O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso. 6Awọn olori alufa si mu owo fadaka na, nwọn si wipe, Ko tọ́ ki a fi i sinu iṣura, nitoripe owo ẹ̀jẹ ni. 7Nwọn si gbìmọ, nwọn si fi rà ilẹ amọ̀koko, lati ma sinkú awọn alejò ninu rẹ̀. 8Nitorina li a ṣe npè ilẹ na ni Ilẹ ẹ̀jẹ, titi di ọjọ oni. 9Nigbana li eyi ti Jeremiah wolĩ sọ wá ṣẹ, pe, Nwọn si mu ọgbọ̀n owo fadaka na, iye owo ẹniti a diyele, ẹniti awọn ọmọ Israeli diyele; 10Nwọn si fi rà ilẹ, amọ̀koko, gẹgẹ bi Oluwa ti làna silẹ fun mi. 11Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i. 12Nigbati a si nkà si i lọrùn lati ọwọ́ awọn olori alufa, ati awọn àgbãgba wá, on kò dahùn kan. 13Nigbana ni Pilatu wi fun u pe, Iwọ ko gbọ́ ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ? 14On kò si dá a ni gbolohun kan; tobẹ̃ ti ẹnu yà Bãlẹ gidigidi. 15Nigba ajọ na, Bãlẹ a mã dá ondè kan silẹ fun awọn enia, ẹnikẹni ti nwọn ba fẹ. 16Nwọn si ni ondè buburu kan lakoko na, ti a npè ni Barabba. 17Nitorina nigbati nwọn pejọ, Pilatu wi fun wọn pe, Tali ẹnyin nfẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Barabba, tabi Jesu ti a npè ni Kristi? 18O sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni nwọn ṣe fi i le on lọwọ. 19Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀. 20Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn agbàgba yi ijọ enia li ọkàn pada lati bère Barabba, ki nwọn si pa Jesu. 21Bãlẹ dahùn o si wi fun wọn pe, Ninu awọn mejeji, ewo li ẹnyin fẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Nwọn wipe, Barabba. 22Pilatu bi wọn pe, Kili emi o ha ṣe si Jesu ẹniti a npè ni Kristi? Gbogbo wọn wipe, Ki a kàn a mọ agbelebu. 23Bãlẹ si bère wipe, Ẽṣe, buburu kili o ṣe? Ṣugbọn nwọn kigbe soke si i pe, Ki a kàn a mọ agbelebu. 24Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o. 25Nigbana ni gbogbo enia dahùn, nwọn si wipe, Ki ẹjẹ rẹ̀ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa. 26Nigbana li o da Barabba silẹ fun wọn. Ṣugbọn o nà Jesu, o si fi i le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. 27Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. 28Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. 29Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. 30Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. 31Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu. 32Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀. 33Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Golgota, eyini ni, Ibi agbari, 34Nwọn fi ọti kikan ti a dàpọ mọ orõrò fun u lati mu: nigbati o si tọ́ ọ wò, o kọ̀ lati mu u. 35Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu, nwọn pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gègé le e: ki eyi ti wolĩ wi ba le ṣẹ, pe, Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn aṣọ ileke mi ni nwọn ṣẹ gègé le. 36Nwọn si joko, nwọn nṣọ ọ nibẹ̀. 37Nwọn si fi ọ̀ran ifisùn rẹ̀ ti a kọ si igberi rẹ̀, EYI NI JESU ỌBA AWỌN JU. 38Nigbana li a kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi. 39Awọn ti nkọja lọ si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, 40Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá. 41Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, 42O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. 43O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi. 44Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna. 45Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. 46Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? 47Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọkunrin yi npè Elijah. 48Lojukanna ọkan ninu wọn si sare, o mu kànìnkànìn, o tẹ̀ ẹ bọ̀ inu ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o si fifun u mu. 49Awọn iyokù wipe, Ẹ fi silẹ̀, ẹ jẹ ki a mã wò bi Elijah yio wá gbà a là. 50Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. 51Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; 52Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, 53Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia. 54Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe. 55Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u: 56Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede. 57Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu: 58O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u. 59Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i, 60O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ. 61Maria Magdalene si wà nibẹ̀, ati Maria keji, nwọn joko dojukọ ibojì na. 62Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu, 63Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde. 64Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju. 65Pilatu wi fun wọn pe, Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mã lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e. 66Bẹ̃ni nwọn lọ, nwọn si se iboji na daju, nwọn fi edídí dí okuta na, nwọn si yàn iṣọ.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\