IFIHÀN 15

1MO si ri àmi miran li ọrun ti o tobi ti o si yanilẹnu, awọn angẹli meje ti o ni awọn iyọnu meje ikẹhin, nitori ninu wọn ni ibinu Ọlọrun de opin. 2Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun. 3Nwọn si nkọ orin ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ati orin ti Ọdọ-Agutan, wipe, Titobi ati iyanu ni awọn iṣẹ rẹ, Oluwa Ọlọrun Olodumare; ododo ati otitọ li ọ̀na rẹ, iwọ Ọba awọn orilẹ-ede. 4Tani kì yio bẹ̀ru, Oluwa, ti kì yio si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mimọ́: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio si wá, ti yio si foribalẹ niwaju rẹ; nitori a ti fi idajọ rẹ hàn. 5Lẹhin na mo si wò, si kiyesi i, a ṣí tẹmpili agọ́ ẹrí li ọrun silẹ: 6Awọn angẹli meje na si ti inu tẹmpili jade wá, nwọn ni iyọnu meje nì, a wọ̀ wọn li aṣọ ọgbọ funfun ti ndan, a si fi àmure wura dì wọn li õkan àiya. 7Ati ọkan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì fi ìgo wura meje fun awọn angẹli meje na, ti o kún fun ibinu Ọlọrun, ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai. 8Tẹmpili na si kún fun ẹ̃fin lati inu ogo Ọlọrun ati agbara rẹ̀ wá; ẹnikẹni kò si le wọ̀ inu tẹmpili na lọ titi a fi mu iyọnu mejeje awọn angẹli meje na ṣẹ.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\