IFIHÀN 19

1LẸHIN nkan wọnyi mo gbọ́ ohùn nla li ọrun bi ẹnipe ti ọ̀pọlọpọ enia, nwipe Halleluiah; ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọlá agbara. 2Nitori otitọ ati ododo ni idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ àgbere nla nì, ti o fi àgbere rẹ̀ ba ilẹ aiye jẹ, o si ti gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ rẹ̀. 3Ati lẹ̃keji nwọn wipe, Halleluiah. Ẹ̃fin rẹ̀ si gòke lọ lai ati lailai. 4Awọn àgba mẹrinlelogun nì, ati awọn ẹda alãye mẹrin nì si wolẹ, nwọn si foribalẹ fun Ọlọrun ti o joko lori itẹ́, wipe, Amin; Halleluiah. 5Ohùn kan si ti ibi itẹ́ na jade wá, wipe, Ẹ mã yìn Ọlọrun wa, ẹnyin iranṣẹ rẹ̀ gbogbo, ẹnyin ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ewe ati àgba. 6Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ati bi iró omi pupọ̀, ati bi iró ãrá nlanla, nwipe Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, njọba. 7Ẹ jẹ ki a yọ̀, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rẹ̀ si ti mura tan. 8On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wíwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣẹ ododo awọn enia mimọ́. 9O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Ibukún ni fun awọn ti a pè si àse-alẹ igbeyawo Ọdọ-Agutan. O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ọ̀rọ otitọ Ọlọrun. 10Mo si wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ lati foribalẹ fun u. O si wi fun mi pe, Wò o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ ti nwọn di ẹrí Jesu mu: foribalẹ fun Ọlọrun: nitoripe ẹrí Jesu li ẹmí isọtẹlẹ. 11Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun. 12Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. 13A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun. 14Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun. 15Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mã fi ṣá awọn orilẹ-ède: on o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare. 16O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA. 17Mo si ri angẹli kan duro ninu õrùn; o si fi ohùn rara kigbe, o nwi fun gbogbo awọn ẹiyẹ ti nfò li agbedemeji ọrun pe, Ẹ wá, ẹ si kó ara nyin jọ pọ̀ si àse-alẹ nla Ọlọrun; 18Ki ẹnyin ki o le jẹ ẹran-ara awọn ọba, ati ẹran-ara awọn olori ogun, ati ẹran-ara awọn enia alagbara, ati ẹran awọn ẹṣin, ati ti awọn ti o joko lori wọn, ati ẹran-ara enia gbogbo, ati ti omnira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgba. 19Mo si ri ẹranko na ati awọn ọba aiye, ati awọn ogun wọn ti a gbájọ lati ba ẹniti o joko lori ẹṣin na ati ogun rẹ̀ jagun. 20A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ̀, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ̀, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lãye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jò. 21Awọn iyokù li a si fi idà ẹniti o joko lori ẹṣin na pa, ani idà ti o ti ẹnu rẹ̀ jade: gbogbo awọn ẹiyẹ si ti ipa ẹran-ara wọn yó.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\