ROMU 12

1NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na. 2Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé. 3Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wà ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o máṣe rò ara rẹ̀ jù bi o ti yẹ ni rirò lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntun-wọnsìn, bi Ọlọrun ti fi ìwọn igbagbọ́ fun olukuluku. 4Nitori gẹgẹ bi awa ti li ẹ̀ya pipọ ninu ara kan, ti gbogbo ẹ̀ya kò si ni iṣẹ kanna: 5Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀. 6Njẹ bi awa si ti nri ọ̀tọ ọ̀tọ ẹ̀bun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a mã sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọn igbagbọ́; 7Tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹniti nkọ́ni, ki o kọjusi kíkọ́; 8Tabi ẹniti o ngbàni niyanju, si igbiyanju: ẹniti o nfi funni ki o mã fi inu kan ṣe e; ẹniti nṣe olori, ki o mã ṣe e li oju mejeji; ẹniti nṣãnu, ki o mã fi inu didùn ṣe e. 9Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere. 10Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju. 11Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa; 12Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura; 13Ẹ mã pese fun aini awọn enia mimọ́; ẹ fi ara nyin fun alejò iṣe. 14Ẹ mã súre fun awọn ti nṣe inunibini si nyin: ẹ mã sure, ẹ má si ṣepè. 15Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun. 16Ẹ mã wà ni inu kanna si ara nyin. Ẹ máṣe tọju ohun gíga, ṣugbọn ẹ mã tẹle awọn onirẹlẹ. Ẹ máṣe jẹ ọlọ́gbọn li oju ara nyin. 17Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. Ẹ mã pèse ohun ti o tọ́ niwaju gbogbo enia. 18Bi o le ṣe, bi o ti wà ni ipa ti nyin, ẹ mã wà li alafia pẹlu gbogbo enia. 19Olufẹ, ẹ máṣe gbẹsan ara nyin, ṣugbọn ẹ fi àye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan. 20Ṣugbọn bi ebi ba npa ọtá rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba ngbẹ ẹ, fun u li omi mu: ni ṣiṣe bẹ̃ iwọ ó kó ẹyín ina le e li ori. 21Maṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu.


Copyrighted Material
Learn More

will be added

X\